Mat 22:11-14
Mat 22:11-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati ọba na wá iwò awọn ti o wá jẹun, o ri ọkunrin kan nibẹ̀ ti kò wọ̀ aṣọ iyawo: O si bi i pe, Ọrẹ́, iwọ ti ṣe wọ̀ ìhin wá laini aṣọ iyawo? Kò si le fọhùn. Nigbana li ọba wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ di i tọwọ tẹsẹ, ẹ gbé e kuro, ki ẹ si sọ ọ sinu òkunkun lode; nibẹ̀ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà. Nitori ọ̀pọlọpọ li a pè, ṣugbọn diẹ li a yàn.
Mat 22:11-14 Yoruba Bible (YCE)
“Nígbà tí ọba wọlé láti wo àwọn tí wọn ń jẹun, ó rí ọkunrin kan níbẹ̀ tí kò wọ aṣọ igbeyawo. Ọba bi í pé, ‘Arakunrin, báwo ni o ti ṣe wọ ìhín láì ní aṣọ igbeyawo?’ Ṣugbọn kẹ́kẹ́ pamọ́ ọkunrin náà lẹ́nu. Ọba bá pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Ẹ dì í tọwọ́-tẹsẹ̀, kí ẹ sọ ọ́ sinu òkùnkùn biribiri. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.’ “Nítorí ọpọlọpọ ni a pè, ṣugbọn àwọn díẹ̀ ni a yàn.”
Mat 22:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ṣùgbọ́n nígbà tí ọba sì wọlé wá láti wo àwọn àlejò tí a pè, ó sì rí ọkùnrin kan nínú wọn tí kò wọ aṣọ ìgbéyàwó. Ọba sì bi í pé, ‘Ọ̀rẹ́, báwo ni ìwọ ṣe wà níhìn-ín yìí láìní aṣọ ìgbéyàwó?’ Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà kò ní ìdáhùn kankan. “Nígbà náà ni ọba wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ dì í tọwọ́ tẹsẹ̀, kí ẹ sì sọ ọ́ sínú òkùnkùn lóde níbi tí ẹkún àti ìpayínkeke wà.’ “Nítorí ọ̀pọ̀ ni a pè ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a yàn.”