Mat 21:8-11
Mat 21:8-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀pọ ijọ enia tẹ́ aṣọ wọn si ọ̀na; ẹlomiran ṣẹ́ ẹka igi wẹ́wẹ́, nwọn si fún wọn si ọ̀na. Ijọ enia ti nlọ niwaju, ati eyi ti ntọ̀ wọn lẹhin, nkigbe wipe, Hosanna fun Ọmọ Dafidi: Olubukun li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa; Hosanna loke ọrun. Nigbati o de Jerusalemu, gbogbo ilu mì titi, wipe, Tani yi? Ijọ enia si wipe, Eyi ni Jesu wolĩ, lati Nasareti ti Galili.
Mat 21:8-11 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀pọ̀ ninu àwọn eniyan tẹ́ aṣọ wọn sọ́nà; àwọn mìíràn ya ẹ̀ka igi, wọ́n tẹ́ wọn sọ́nà. Àwọn èrò tí ń lọ níwájú, ati àwọn tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn wá ń kígbe pé, “Hosana fún Ọmọ Dafidi, olùbùkún ni ẹni tí ó wá lórúkọ Oluwa. Ògo ni fún Ọlọrun lókè ọ̀run.” Nígbà tí Jesu wọ Jerusalẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì. Àwọn ará ìlú ń bèèrè pé, “Ta nìyí?” Àwọn èrò tí ń bọ̀ wá sì dá wọn lóhùn pé, “Jesu, wolii, láti ìlú Nasarẹti ti Galili ni.”
Mat 21:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tẹ́ aṣọ wọn sí ojú ọ̀nà níwájú rẹ̀, ẹlòmíràn ṣẹ́ ẹ̀ka igi wẹ́wẹ́ wọ́n sì tẹ́ wọn sí ojú ọ̀nà. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ níwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú ń kígbe pé, “Hosana fún ọmọ Dafidi!” “Olùbùkún ni fún ẹni tí ó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa!” “Hosana ní ibi gíga jùlọ!” Bí Jesu sì ti ń wọ Jerusalẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara wọn pé, “Ta nìyìí?” Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì dáhùn pé, “Èyí ni Jesu, wòlíì náà láti Nasareti ti Galili.”