Mat 21:33-44

Mat 21:33-44 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹ gbọ́ owe miran; Bãle ile kan wà ti o gbìn ajara, o si sọgba yi i ká, o wà ibi ifunti sinu rẹ̀, o kọ́ ile-iṣọ, o si fi ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba, o si lọ si ajò. Nigbati akokò eso sunmọ etile, o ràn awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ si awọn oluṣọgba na, ki nwọn ki o le gbà wá ninu eso rẹ̀. Awọn oluṣọgba si mu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, nwọn lù ekini, nwọn pa ekeji, nwọn si sọ ẹkẹta li okuta. O si tun rán awọn ọmọ-ọdọ miran ti o jù awọn ti iṣaju lọ: nwọn si ṣe bẹ̃ si wọn gẹgẹ. Ṣugbọn ni ikẹhin gbogbo wọn, o rán ọmọ rẹ̀ si wọn, o wipe, Nwọn o ṣe ojuṣãju fun ọmọ mi. Ṣugbọn nigbati awọn oluṣọgba ri ọmọ na, nwọn wi fun ara wọn pe, Eyiyi li arole; ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki a si kó ogún rẹ̀. Nwọn si mu u, nwọn wọ́ ọ jade kuro ninu ọgbà ajara na, nwọn si pa a. Njẹ nigbati oluwa ọgbà ajara ba de, kini yio ṣe si awọn oluṣọgba wọnni? Nwọn wi fun u pe, Yio pa awọn enia buburu wọnni run ni ipa òṣi, yio si fi ọgbà ajara rẹ̀ ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba miran, awọn ti o ma fi eso rẹ̀ fun u lakokò. Jesu wi fun wọn pe, Ẹnyin ko ti kà a ninu iwe mimọ́ pe, Okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ, on na li o si di pàtaki igun ile: eyi ni iṣẹ Oluwa, o si jẹ iyanu li oju wa? Nitorina emi wi fun nyin pe, A o gbà ijọba Ọlọrun lọwọ nyin, a o si fifun orilẹ-ede ti yio ma mu eso rẹ̀ wá. Ẹnikẹni ti o ba ṣubu lù okuta yi yio fọ́: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ṣubu lù, yio lọ̀ ọ lũlu.

Mat 21:33-44 Yoruba Bible (YCE)

Jesu ní, “Ẹ tún gbọ́ òwe mìíràn. Baba kan wà tí ó gbin èso àjàrà sí oko rẹ̀. Ó ṣe ọgbà yí i ká; ó wa ilẹ̀ ìfúntí sibẹ; ó kọ́ ilé-ìṣọ́ sí i; ó bá fi í lé àwọn alágbàro lọ́wọ́, ó lọ sí ìdálẹ̀. Nígbà tí ó tó àkókò ìkórè, ó rán àwọn ẹrú rẹ̀ sí àwọn alágbàro náà láti gba ìpín tirẹ̀ wá ninu èso rẹ̀. Ṣugbọn àwọn alágbàro náà mú àwọn ẹrú rẹ̀, wọ́n na àwọn kan, wọ́n pa àwọn kan, wọ́n sọ àwọn mìíràn ní òkúta. Sibẹ ó tún rán àwọn ẹrú mìíràn tí wọ́n pọ̀ ju àwọn ti àkọ́kọ́ lọ; ṣugbọn bákan náà ni àwọn alágbàro yìí ṣe sí wọn. Ní ìgbẹ̀yìn ó wá rán ọmọ rẹ̀ sí wọn, ó ní, ‘Wọn óo bu ọlá fún ọmọ mi.’ Ṣugbọn nígbà tí àwọn alágbàro náà rí ọmọ rẹ̀, wọ́n wí láàrin ara wọn pé, ‘Àrólé rẹ̀ ni èyí. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí ogún rẹ̀ lè di tiwa.’ Wọ́n bá mú un, wọ́n tì í jáde kúrò ninu ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á. “Nítorí náà, nígbà tí ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà bá dé, kí ni yóo ṣe sí àwọn alágbàro náà?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Pípa ni yóo pa àwọn olubi náà, yóo fi ọgbà àjàrà rẹ̀ lé àwọn alágbàro mìíràn lọ́wọ́, tí yóo fún un ní èso ní àkókò tí ó wọ̀.” Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mímọ́ pé, ‘Òkúta tí àwọn tí ń mọlé kọ̀ sílẹ̀, òun ni ó di pataki ní igun ilé. Iṣẹ́ Oluwa ni èyí, ìyanu ni ó jẹ́ lójú wa.’ “Nítorí èyí mo sọ fun yín pé a gba ìjọba Ọlọrun lọ́wọ́ yín, a fi fún orílẹ̀-èdè tí yóo so èso tí ó yẹ. [ Bí eniyan bá kọlu òkúta yìí, olúwarẹ̀ yóo rún wómúwómú. Bí òkúta yìí bá bọ́ lu eniyan, yóo rẹ́ olúwarẹ̀ pẹ́tẹ́pẹ́tẹ́.”]

Mat 21:33-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ẹ gbọ́ òwe mìíràn: Baálé ilé kan tí ó gbin ọgbà àjàrà, ó ṣe ọgbà yìí ká, ó wá ibi ìfúntí sínú rẹ̀, ó kọ́ ilé ìṣọ́. Ó sì fi oko náà ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn àgbẹ̀ kan, ó sì lọ sí ìrìnàjò. Nígbà ti àkókò ìkórè súnmọ́, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn àgbẹ̀ náà láti gba èyí ti ó jẹ tirẹ̀ wá. “Ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọn lu ẹni kìn-ín-ní, wọn pa èkejì, wọ́n si sọ ẹ̀kẹta ní òkúta. Ó sì tún rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn àwọn tí ó ju ti ìṣáájú lọ. Wọ́n sì túnṣe bí ti àkọ́kọ́ sí àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú. Níkẹyìn, baálé ilé yìí rán ọmọ rẹ̀ pàápàá sí wọn. Ó wí pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ mi.’ “Ṣùgbọ́n bí àwọn alágbàtọ́jú wọ̀nyí ti rí ọmọ náà lókèèrè, wọ́n wí fún ara wọn pé, ‘Èyí ni àrólé náà. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí a sì jogún rẹ̀.’ Wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú ọgbà àjàrà náà, wọ́n sì pa á. “Ǹjẹ́ nígbà tí olúwa ọgbà àjàrà bá dé, kí ni yóò ṣe sí àwọn olùṣọ́gbà wọ̀n-ọn-nì?” Wọ́n wí pé, “Òun yóò pa àwọn ènìyàn búburú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú mìíràn tí yóò fún un ní èso tirẹ̀ lásìkò ìkórè.” Jesu wí fún wọ́n pé, “Àbí ẹ̀yin kò kà á nínú ìwé Mímọ́ pé: “ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, ni ó di pàtàkì igun ilé; iṣẹ́ Olúwa ni èyí, ó sì jẹ́ ìyanu ní ojú wa’? “Nítorí náà èmi wí fún yín, a ó gba ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ wá. Ẹni tí ó bá ṣubú lu òkúta yìí yóò di fífọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí òun bá ṣubú lù yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”