Mat 21:1-46

Mat 21:1-46 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBATI nwọn sunmọ eti Jerusalemu, ti nwọn de Betfage li òke Olifi, nigbana ni Jesu rán awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ meji lọ. O wi fun wọn pe, Ẹ lọ si iletò ti o kọju si nyin, lọgan ẹnyin o ri kẹtẹkẹtẹ kan ti a so ati ọmọ rẹ̀ pẹlu: ẹ tú wọn, ki ẹ si fà wọn fun mi wá. Bi ẹnikẹni ba si wi nkan fun nyin, ẹnyin o wipe, Oluwa ni ifi wọn ṣe; lọgán ni yio si rán wọn wá. Gbogbo eyi li a ṣe, ki eyi ti a ti sọ lati ẹnu wolĩ wá ki o le ṣẹ, pe, Ẹ sọ fun ọmọbinrin Sioni pe, Kiyesi i, Ọba rẹ mbọ̀ wá sọdọ rẹ, o ni irẹlẹ, o joko lori kẹtẹkẹtẹ, ati lori ọmọ kẹtẹkẹtẹ. Awọn ọmọ-ẹhin na si lọ, nwọn ṣe bi Jesu ti wi fun wọn. Nwọn si fà kẹtẹkẹtẹ na wá, ati ọmọ rẹ̀, nwọn si tẹ́ aṣọ wọn si ẹhin wọn, nwọn si gbé Jesu kà a. Ọ̀pọ ijọ enia tẹ́ aṣọ wọn si ọ̀na; ẹlomiran ṣẹ́ ẹka igi wẹ́wẹ́, nwọn si fún wọn si ọ̀na. Ijọ enia ti nlọ niwaju, ati eyi ti ntọ̀ wọn lẹhin, nkigbe wipe, Hosanna fun Ọmọ Dafidi: Olubukun li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa; Hosanna loke ọrun. Nigbati o de Jerusalemu, gbogbo ilu mì titi, wipe, Tani yi? Ijọ enia si wipe, Eyi ni Jesu wolĩ, lati Nasareti ti Galili. Jesu si wọ̀ inu tẹmpili Ọlọrun lọ, o si lé gbogbo awọn ẹniti ntà, ati awọn ti nrà ni tẹmpili jade, o si yi tabili awọn onipaṣiparọ owo danù, ati ijoko awọn ti ntà ẹiyẹle. O si wi fun wọn pe, A ti kọ ọ pe, Ile adura li a ó ma pè ile mi; ṣugbọn ẹnyin sọ ọ di ihò ọlọṣà. Ati awọn afọju ati awọn amukun wá sọdọ rẹ̀ ni tẹmpili; o si mu wọn larada. Ṣugbọn nigbati awọn olori alufa ati awọn akọwe ri ohun iyanu ti o ṣe, ati bi awọn ọmọ kekeke ti nke ni tẹmpili, wipe, Hosanna fun Ọmọ Dafidi; inu bi wọn gidigidi, Nwọn si wi fun u pe, Iwọ gbọ́ eyiti awọn wọnyi nwi? Jesu si wi fun wọn pe, Bẹ̃ni; ẹnyin kò ti kà a ninu iwe pe, Lati ẹnu awọn ọmọ-ọwọ́ ati awọn ọmọ-ọmu ni iwọ ti mu iyìn pé? O si fi wọn silẹ, o jade kuro ni ilu na lọ si Betani; o wọ̀ sibẹ̀. Nigbati o di owurọ̀, bi o ti npada bọ̀ si Jerusalemu, ebi npa a. Nigbati o ri igi ọ̀pọtọ li ọ̀na, o lọ sibẹ̀, kò si ri ohun kan lori rẹ̀, bikoṣe kìki ewé, o si wi fun u pe, Ki eso ki o má so lori rẹ lati oni lọ titi lailai. Lojukanna igi ọpọtọ na gbẹ. Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i, ẹnu yà wọn, nwọn wipe, Igi ọpọtọ yi mà tete gbẹ? Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́, ti ẹ kò ba si ṣiyemeji, ẹnyin kì yio ṣe kìki eyi ti a ṣe si igi ọpọtọ yi, ṣugbọn bi ẹnyin ba tilẹ wi fun òke yi pe, Ṣidi, ki o si bọ́ sinu okun, yio ṣẹ. Ohunkohun gbogbo ti ẹnyin ba bère ninu adura pẹlu igbagbọ́, ẹnyin o ri gbà. Nigbati o si de inu tẹmpili, awọn olori alufa ati awọn àgba awọn enia wá sọdọ rẹ̀ bi o ti nkọ́ awọn enia; nwọn wipe, Aṣẹ wo ni iwọ fi nṣe nkan wọnyi? tali o si fun ọ li aṣẹ yi? Jesu si dahun o si wi fun wọn pe, Emi ó si bi nyin lẽre ohun kan pẹlu, bi ẹnyin ba sọ fun mi, emi o si sọ fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi: Baptismu Johanu, nibo li o ti wá? lati ọrun wá ni, tabi lati ọdọ enia? Nwọn si ba ara wọn gbèro, wipe, Bi awa ba wipe, Lati ọrun wá ni, on o wi fun wa pe, Ẽha ti ṣe ti ẹnyin ko fi gbà a gbọ́? Ṣugbọn bi awa ba si wipe, Lati ọdọ enia; awa mbẹ̀ru ijọ enia, nitori gbogbo wọn kà Johanu si wolĩ. Nwọn si da Jesu lohùn, wipe, Awa ko mọ. O si wi fun wọn pe, Njẹ emi kì yio si wi fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi. Ṣugbọn kili ẹnyin nrò? Ọkunrin kan wà ti o li ọmọ ọkunrin meji; o tọ̀ ekini wá, o si wipe, Ọmọ, lọ iṣiṣẹ loni ninu ọgba ajara mi. O si dahùn wipe, Emi kì yio lọ: ṣugbọn o ronu nikẹhin, o si lọ. O si tọ̀ ekeji wá, o si wi bẹ̃ gẹgẹ. O si dahùn wi fun u pe, Emi o lọ, baba: kò si lọ. Ninu awọn mejeji, ewo li o ṣe ifẹ baba rẹ̀? Nwọn wi fun u pe, Eyi ekini. Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, awọn agbowode ati awọn panṣaga ṣiwaju nyin lọ si ijọba Ọlọrun. Nitori Johanu ba ọ̀na ododo tọ̀ nyin wá, ẹnyin kò si gbà a gbọ́: ṣugbọn awọn agbowode ati awọn panṣaga gbà a gbọ́: ṣugbọn ẹnyin, nigbati ẹnyin si ri i, ẹ kò ronupiwada nikẹhin, ki ẹ le gbà a gbọ́. Ẹ gbọ́ owe miran; Bãle ile kan wà ti o gbìn ajara, o si sọgba yi i ká, o wà ibi ifunti sinu rẹ̀, o kọ́ ile-iṣọ, o si fi ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba, o si lọ si ajò. Nigbati akokò eso sunmọ etile, o ràn awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ si awọn oluṣọgba na, ki nwọn ki o le gbà wá ninu eso rẹ̀. Awọn oluṣọgba si mu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, nwọn lù ekini, nwọn pa ekeji, nwọn si sọ ẹkẹta li okuta. O si tun rán awọn ọmọ-ọdọ miran ti o jù awọn ti iṣaju lọ: nwọn si ṣe bẹ̃ si wọn gẹgẹ. Ṣugbọn ni ikẹhin gbogbo wọn, o rán ọmọ rẹ̀ si wọn, o wipe, Nwọn o ṣe ojuṣãju fun ọmọ mi. Ṣugbọn nigbati awọn oluṣọgba ri ọmọ na, nwọn wi fun ara wọn pe, Eyiyi li arole; ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki a si kó ogún rẹ̀. Nwọn si mu u, nwọn wọ́ ọ jade kuro ninu ọgbà ajara na, nwọn si pa a. Njẹ nigbati oluwa ọgbà ajara ba de, kini yio ṣe si awọn oluṣọgba wọnni? Nwọn wi fun u pe, Yio pa awọn enia buburu wọnni run ni ipa òṣi, yio si fi ọgbà ajara rẹ̀ ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba miran, awọn ti o ma fi eso rẹ̀ fun u lakokò. Jesu wi fun wọn pe, Ẹnyin ko ti kà a ninu iwe mimọ́ pe, Okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ, on na li o si di pàtaki igun ile: eyi ni iṣẹ Oluwa, o si jẹ iyanu li oju wa? Nitorina emi wi fun nyin pe, A o gbà ijọba Ọlọrun lọwọ nyin, a o si fifun orilẹ-ede ti yio ma mu eso rẹ̀ wá. Ẹnikẹni ti o ba ṣubu lù okuta yi yio fọ́: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ṣubu lù, yio lọ̀ ọ lũlu. Nigbati awọn olori alufa ati awọn Farisi gbọ́ owe rẹ̀ nwọn woye pe awọn li o mba wi. Ṣugbọn nigbati nwọn nwá ọ̀na ati gbé ọwọ́ le e, nwọn bẹ̀ru ijọ enia, nitoriti nwọn kà a si wolĩ.

Mat 21:1-46 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jerusalẹmu, tí wọ́n dé Bẹtifage ní Òkè Olifi, Jesu rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn meji lọ ṣiwaju. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí ìletò tí ó wà ní ọ̀kánkán yín yìí. Bí ẹ bá ti wọ inú rẹ̀, ẹ óo rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n so mọ́lẹ̀, pẹlu ọmọ rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ mú wọn wá fún mi. Bí ẹnìkan bá bi yín ní nǹkankan, ẹ dá a lóhùn pé, ‘Oluwa nílò wọn.’ Lẹsẹkẹsẹ wọn yóo jẹ́ kí ẹ mú wọn wá.” Kí ọ̀rọ̀ tí wolii nì sọ lè ṣẹ pé, “Ẹ sọ fún ọdọmọbinrin, Sioni, pé, Wo ọba rẹ tí ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ; pẹlu ìrẹ̀lẹ̀, ó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ẹranko tí à ń lò láti rẹrù.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà lọ, wọ́n ṣe bí Jesu ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ati ọmọ rẹ̀ wá, wọ́n tẹ́ aṣọ lé wọn lórí, Jesu bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn. Ọ̀pọ̀ ninu àwọn eniyan tẹ́ aṣọ wọn sọ́nà; àwọn mìíràn ya ẹ̀ka igi, wọ́n tẹ́ wọn sọ́nà. Àwọn èrò tí ń lọ níwájú, ati àwọn tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn wá ń kígbe pé, “Hosana fún Ọmọ Dafidi, olùbùkún ni ẹni tí ó wá lórúkọ Oluwa. Ògo ni fún Ọlọrun lókè ọ̀run.” Nígbà tí Jesu wọ Jerusalẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì. Àwọn ará ìlú ń bèèrè pé, “Ta nìyí?” Àwọn èrò tí ń bọ̀ wá sì dá wọn lóhùn pé, “Jesu, wolii, láti ìlú Nasarẹti ti Galili ni.” Jesu bá wọ inú Tẹmpili lọ, ó lé gbogbo àwọn tí wọn ń tà, tí wọn ń rà kúrò níbẹ̀. Ó ti tabili àwọn tí wọn ń ṣe pàṣípààrọ̀ owó ṣubú. Ó da ìsọ̀ àwọn tí wọn ń ta ẹyẹlé rú. Ó sọ fún wọn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ilé adura ni ilé mi jẹ́,’ ṣugbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibi tí àwọn ọlọ́ṣà ń sápamọ́ sí.” Àwọn afọ́jú ati àwọn arọ bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ninu Tẹmpili, ó sì wò wọ́n sàn. Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin rí àwọn ohun ìyanu tí Jesu ṣe, tí wọ́n tún gbọ́ bí àwọn ọmọde ti ń kígbe ninu Tẹmpili pé, “Hosana fún Ọmọ Dafidi,” inú wọn ru. Wọ́n sọ fún un pé, “O kò gbọ́ ohun tí àwọn wọnyi ń wí ni?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo gbọ́. Ẹ kò tíì kà á pé, ‘Lẹ́nu àwọn ọmọ-ọwọ́ ati àwọn ọmọ-ọmú ni ìwọ ti gba ìyìn pípé?’ ” Ó bá fi wọ́n sílẹ̀, ó sì jáde kúrò lọ sí Bẹtani. Níbẹ̀ ni ó gbé sùn. Lówùúrọ̀ ọjọ́ keji, bí ó ti ń pada lọ sinu ìlú, ebi ń pa á. Bí ó ti rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́nà, ó yà lọ sí ìdí rẹ̀, ṣugbọn, kò rí nǹkankan lórí rẹ̀ àfi kìkì ewé. Ó bá sọ fún un pé, “O kò ní so mọ́ laelae.” Lẹsẹkẹsẹ ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà bá gbẹ! Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n ń sọ pé, “Báwo ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ṣe gbẹ lẹsẹkẹsẹ.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ bá ní igbagbọ, láì ṣiyèméjì, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí nìkan kọ́ ni ẹ óo ṣe, ṣugbọn bí ẹ bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Dìde, kí o lọ rì sinu òkun,’ bẹ́ẹ̀ ni yóo rí. Ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ninu adura, bí ẹ bá gbàgbọ́, ẹ óo rí i gbà.” Nígbà tí Jesu dé inú Tẹmpili, bí ó ti ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́, àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà ìlú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Irú agbára wo ni o fi ń ṣe nǹkan wọnyi? Ta ni ó sì fún ọ ní agbára náà?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi náà yóo bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan. Tí ẹ bá dá mi lóhùn, èmi náà yóo wá sọ irú agbára tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi. Ìrìbọmi tí Johanu ń ṣe, báwo ló ti jẹ́: ṣé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá ni tabi láti ọ̀dọ̀ eniyan?” Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn jiyàn, wọ́n ń wí pé, “Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run ni,’ yóo bi wá pé, ‘Kí ló dé tí ẹ kò fi gbà á gbọ́?’ Bí a bá sì wí pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ eniyan ni,’ a bẹ̀rù àwọn eniyan, nítorí gbogbo eniyan gbà pé wolii tòótọ́ ni Johanu.” Wọ́n bá dá Jesu lóhùn pé, “Àwa kò mọ̀.” Ó bá sọ fún wọn pé, “Èmi náà kò ní sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi fun yín.” Ó wá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ rò nípa èyí? Ọkunrin kan ní ọmọ meji. Ó lọ sọ́dọ̀ ekinni, ó sọ fún un pé, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ ninu ọgbà àjàrà mi lónìí.’ Ọmọ náà dá a lóhùn pé, ‘N kò ní lọ.’ Ṣugbọn lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ó ronupiwada, ó bá lọ. Ọkunrin náà lọ sọ́dọ̀ ọmọ keji, ó sọ fún un bí ó ti sọ fún ekinni. Ọmọ náà dá a lóhùn pé, ‘Ó dára, mo gbọ́, Baba!’ Ṣugbọn kò lọ. Ninu àwọn mejeeji, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba rẹ̀?” Wọ́n ní, “Ekinni ni.” Jesu bá sọ fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àwọn agbowó-odè ati àwọn aṣẹ́wó yóo ṣáájú yín wọ ìjọba Ọlọrun. Nítorí Johanu wá sọ́dọ̀ yín ní ọ̀nà òdodo, ṣugbọn ẹ kò gbà á gbọ́. Ṣugbọn àwọn agbowó-odè ati àwọn aṣẹ́wó gbà á gbọ́. Lẹ́yìn tí ẹ rí èyí, ẹ kò ronupiwada kí ẹ gbà á gbọ́.” Jesu ní, “Ẹ tún gbọ́ òwe mìíràn. Baba kan wà tí ó gbin èso àjàrà sí oko rẹ̀. Ó ṣe ọgbà yí i ká; ó wa ilẹ̀ ìfúntí sibẹ; ó kọ́ ilé-ìṣọ́ sí i; ó bá fi í lé àwọn alágbàro lọ́wọ́, ó lọ sí ìdálẹ̀. Nígbà tí ó tó àkókò ìkórè, ó rán àwọn ẹrú rẹ̀ sí àwọn alágbàro náà láti gba ìpín tirẹ̀ wá ninu èso rẹ̀. Ṣugbọn àwọn alágbàro náà mú àwọn ẹrú rẹ̀, wọ́n na àwọn kan, wọ́n pa àwọn kan, wọ́n sọ àwọn mìíràn ní òkúta. Sibẹ ó tún rán àwọn ẹrú mìíràn tí wọ́n pọ̀ ju àwọn ti àkọ́kọ́ lọ; ṣugbọn bákan náà ni àwọn alágbàro yìí ṣe sí wọn. Ní ìgbẹ̀yìn ó wá rán ọmọ rẹ̀ sí wọn, ó ní, ‘Wọn óo bu ọlá fún ọmọ mi.’ Ṣugbọn nígbà tí àwọn alágbàro náà rí ọmọ rẹ̀, wọ́n wí láàrin ara wọn pé, ‘Àrólé rẹ̀ ni èyí. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí ogún rẹ̀ lè di tiwa.’ Wọ́n bá mú un, wọ́n tì í jáde kúrò ninu ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á. “Nítorí náà, nígbà tí ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà bá dé, kí ni yóo ṣe sí àwọn alágbàro náà?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Pípa ni yóo pa àwọn olubi náà, yóo fi ọgbà àjàrà rẹ̀ lé àwọn alágbàro mìíràn lọ́wọ́, tí yóo fún un ní èso ní àkókò tí ó wọ̀.” Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mímọ́ pé, ‘Òkúta tí àwọn tí ń mọlé kọ̀ sílẹ̀, òun ni ó di pataki ní igun ilé. Iṣẹ́ Oluwa ni èyí, ìyanu ni ó jẹ́ lójú wa.’ “Nítorí èyí mo sọ fun yín pé a gba ìjọba Ọlọrun lọ́wọ́ yín, a fi fún orílẹ̀-èdè tí yóo so èso tí ó yẹ. [ Bí eniyan bá kọlu òkúta yìí, olúwarẹ̀ yóo rún wómúwómú. Bí òkúta yìí bá bọ́ lu eniyan, yóo rẹ́ olúwarẹ̀ pẹ́tẹ́pẹ́tẹ́.”] Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi gbọ́ àwọn òwe wọnyi, wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó ń bá wí. Wọ́n bá ń wá ọ̀nà láti mú un, ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan, nítorí àwọn eniyan gbà á bíi wolii.

Mat 21:1-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Bí wọ́n ti súnmọ́ Jerusalẹmu, tí wọ́n dé itòsí ìlú Betfage ní orí òkè Olifi, Jesu sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì, Ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí ìletò tó wà ni tòsí yín, ẹ̀yin yóò rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ti wọ́n so pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ sì mú wọn wá fún mi. Bí ẹnikẹ́ni bá sì béèrè ìdí tí ẹ fi ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ sá à wí pé, Olúwa fẹ́ lo wọn, òun yóò sì rán wọn lọ.” Èyí ṣẹlẹ̀ láti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì ṣẹ pé: “Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Sioni pé, ‘Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, ní ìrẹ̀lẹ̀, ó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.’ ” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sí lọ, wọ́n ṣe bí Jesu ti sọ fún wọn Wọ́n sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, wọ́n tẹ́ aṣọ lé e, Jesu si jókòó lórí rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tẹ́ aṣọ wọn sí ojú ọ̀nà níwájú rẹ̀, ẹlòmíràn ṣẹ́ ẹ̀ka igi wẹ́wẹ́ wọ́n sì tẹ́ wọn sí ojú ọ̀nà. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ níwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú ń kígbe pé, “Hosana fún ọmọ Dafidi!” “Olùbùkún ni fún ẹni tí ó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa!” “Hosana ní ibi gíga jùlọ!” Bí Jesu sì ti ń wọ Jerusalẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara wọn pé, “Ta nìyìí?” Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì dáhùn pé, “Èyí ni Jesu, wòlíì náà láti Nasareti ti Galili.” Jesu sì wọ inú tẹmpili, Ó sì lé àwọn ti ń tà àti àwọn tí ń rà níbẹ̀ jáde. Ó yí tábìlì àwọn onípàṣípàrọ̀ owó dànù, àti tábìlì àwọn tí ó ń ta ẹyẹlé. Ó wí fún wọn pé, “A sá à ti kọ ọ́ pé, ‘Ilé àdúrà ni a ó máa pe ilé mi,’ ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùdó àwọn ọlọ́ṣà.” A sì mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní tẹmpili, ó sì mú wọ́n láradá Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin rí àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá wọ̀nyí, ti wọ́n sì tún ń gbọ́ tí àwọn ọmọdé ń kígbe nínú tẹmpili pé, “Hosana fún ọmọ Dafidi,” inú bí wọn. Wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ ìwọ gbọ́ nǹkan tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí ń sọ?” Jesu sí dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni,” “Àbí ẹ̀yin kò kà á pé ‘Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ ọmú, ni a ó ti máa yìn mí?’ ” Ó sì fi wọ́n sílẹ̀, ó lọ sí Betani. Níbẹ̀ ni ó dúró ní òru náà. Ní òwúrọ̀ bí ó ṣe ń padà sí ìlú, ebi ń pa á. Ó sì ṣàkíyèsí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lẹ́bàá ojú ọ̀nà, ó sì lọ wò ó bóyá àwọn èso wà lórí rẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹyọ kan, ewé nìkan ni ó wà lórí rẹ̀. Nígbà náà ni ó sì wí fún igi náà pé, “Kí èso má tún so lórí rẹ mọ́ láti òní lọ àti títí láé.” Lójúkan náà igi ọ̀pọ̀tọ́ náà sì gbẹ. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí èyí, ẹnu yà wọn, wọ́n béèrè pé, “Báwo ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ṣe gbẹ kíákíá?” Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹ̀yin bá lè ní ìgbàgbọ́ láìṣiyèméjì, nígbà náà ẹ̀yin yóò lè ṣe irú ohun tí a ṣe sí igi ọ̀pọ̀tọ́, Ẹ̀yin yóò lè sọ fún òkè yìí pé, ‘Yí ipò padà sínú Òkun,’ yóò sì rí bẹ́ẹ̀. Bí ẹ̀yin bá gbàgbọ́, ẹ̀yin lè rí ohunkóhun tí ẹ bá béèrè nínú àdúrà gbà.” Jesu wọ tẹmpili, nígbà tí ó ń kọ́ni, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù tọ̀ ọ́ wá. Wọ́n béèrè pé “nípa àṣẹ wo ni o fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí? Ta ni ó sì fún ọ ni àṣẹ yìí?” Jesu sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi yóò si bí yin léèrè ohun kan, bí ẹ̀yin bá lé sọ fún mi, nígbà náà èmi yóò sọ fún yín, àṣẹ tí Èmi fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí. Níbo ni ìtẹ̀bọmi Johanu ti wa? Láti ọ̀run wá ni, tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn.” Wọ́n sì bá ara wọn gbèrò pé, “Bí àwa bá wí pé láti ọ̀run wá ni, òun yóò wí fún wa pé, ‘Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’ Ní ìdàkejì, bí àwa bá sì sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, àwa bẹ̀rù ìjọ ènìyàn, nítorí gbogbo wọ́n ka Johanu sí wòlíì.’ ” Nítorí náà wọ́n sì dá Jesu lóhùn pé, “Àwa kò mọ̀.” Nígbà náà ni ó wí pé, “Nítorí èyí, èmi kò ní sọ àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín. “Kí ni ẹ rò nípa eléyìí? Ọkùnrin kan ti ó ní àwọn ọmọkùnrin méjì. Ó sọ fún èyí ẹ̀gbọ́n pé, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà lónìí.’ “Ó sì dá baba rẹ̀ lóhùn pé, ‘Èmi kò ní í lọ,’ ṣùgbọ́n níkẹyìn ó yí ọkàn padà, ó sì lọ. “Nígbà náà ni baba yìí tún sọ fún èyí àbúrò pé, ‘Lọ ṣiṣẹ́ ní oko.’ Ọmọ náà sì sọ pé, ‘Èmi yóò lọ, baba,’ ṣùgbọ́n kò lọ rárá. “Nínú àwọn méjèèjì yìí, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba wọn?” Gbogbo wọn sì fohùn ṣọ̀kan pé, “Èyí ẹ̀gbọ́n ni.” Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà yóò wọ ìjọba ọ̀run síwájú yín. Nítorí Johanu tọ́ yin wá láti fi ọ̀nà òdodo hàn yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbà á gbọ́, ṣùgbọ́n àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà ronúpìwàdà, bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ rí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, ẹ kọ̀ láti ronúpìwàdà, ẹ kò gbà á gbọ́.” “Ẹ gbọ́ òwe mìíràn: Baálé ilé kan tí ó gbin ọgbà àjàrà, ó ṣe ọgbà yìí ká, ó wá ibi ìfúntí sínú rẹ̀, ó kọ́ ilé ìṣọ́. Ó sì fi oko náà ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn àgbẹ̀ kan, ó sì lọ sí ìrìnàjò. Nígbà ti àkókò ìkórè súnmọ́, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn àgbẹ̀ náà láti gba èyí ti ó jẹ tirẹ̀ wá. “Ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọn lu ẹni kìn-ín-ní, wọn pa èkejì, wọ́n si sọ ẹ̀kẹta ní òkúta. Ó sì tún rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn àwọn tí ó ju ti ìṣáájú lọ. Wọ́n sì túnṣe bí ti àkọ́kọ́ sí àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú. Níkẹyìn, baálé ilé yìí rán ọmọ rẹ̀ pàápàá sí wọn. Ó wí pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ mi.’ “Ṣùgbọ́n bí àwọn alágbàtọ́jú wọ̀nyí ti rí ọmọ náà lókèèrè, wọ́n wí fún ara wọn pé, ‘Èyí ni àrólé náà. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí a sì jogún rẹ̀.’ Wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú ọgbà àjàrà náà, wọ́n sì pa á. “Ǹjẹ́ nígbà tí olúwa ọgbà àjàrà bá dé, kí ni yóò ṣe sí àwọn olùṣọ́gbà wọ̀n-ọn-nì?” Wọ́n wí pé, “Òun yóò pa àwọn ènìyàn búburú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú mìíràn tí yóò fún un ní èso tirẹ̀ lásìkò ìkórè.” Jesu wí fún wọ́n pé, “Àbí ẹ̀yin kò kà á nínú ìwé Mímọ́ pé: “ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, ni ó di pàtàkì igun ilé; iṣẹ́ Olúwa ni èyí, ó sì jẹ́ ìyanu ní ojú wa’? “Nítorí náà èmi wí fún yín, a ó gba ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ wá. Ẹni tí ó bá ṣubú lu òkúta yìí yóò di fífọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí òun bá ṣubú lù yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.” Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi gbọ́ òwe Jesu, wọ́n mọ̀ wí pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn. Wọn wá ọ̀nà láti mú un, ṣùgbọ́n wọn bẹ̀rù ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n gba Jesu gẹ́gẹ́ bí wòlíì.