Mat 20:20-28
Mat 20:20-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni iya awọn ọmọ Sebede ba awọn ọmọ rẹ̀ tọ̀ ọ wá, o bẹ̀ ẹ, o si nfẹ ohun kan li ọwọ́ rẹ̀. O si bi i pe, Kini iwọ nfẹ? O wi fun u pe, Jẹ ki awọn ọmọ mi mejeji ki o mã joko, ọkan li ọwọ́ ọtún rẹ, ọkan li ọwọ́ òsi ni ijọba rẹ. Ṣugbọn Jesu dahùn, o si wipe, Ẹnyin ko mọ̀ ohun ti ẹnyin mbère. Ẹnyin le mu ninu ago ti emi ó mu, ati ki a fi baptismu ti a o fi baptisi mi baptisi nyin? Nwọn wi fun u pe, Awa le ṣe e. O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin o mu ninu ago mi, ati ninu baptismu ti a o fi baptisi mi li a o si fi baptisi nyin; ṣugbọn lati joko li ọwọ́ ọtún ati li ọwọ́ òsi mi, ki iṣe ti emi lati fi funni, bikoṣepe fun kìki awọn ẹniti a ti pèse rẹ̀ silẹ fun lati ọdọ Baba mi wá. Nigbati awọn mẹwa iyokù gbọ́ ọ, nwọn binu si awọn arakunrin wọn mejeji. Ṣugbọn Jesu pè wọn sọdọ rẹ̀, o si wipe, Ẹnyin mọ̀ pe awọn ọba Keferi a ma lò agbara lori wọn, ati awọn ẹni-nla ninu wọn a ma fi ọlá tẹri wọn ba. Ṣugbọn kì yio ri bẹ̃ lãrin nyin: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fẹ pọ̀ ninu nyin, ẹ jẹ ki o ṣe iranṣẹ nyin; Ati ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣe olori ninu nyin, jẹ ki o ma ṣe ọmọ-ọdọ nyin: Ani gẹgẹ bi Ọmọ-enia kò ti wá ki a ṣe iranṣẹ fun u, bikoṣe lati ṣe iranṣẹ funni, ati lati fi ẹmi rẹ̀ ṣe iràpada ọpọlọpọ enia.
Mat 20:20-28 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sebede wá sọ́dọ̀ Jesu pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀. Ó kúnlẹ̀, ó ń bèèrè nǹkankan lọ́dọ̀ rẹ̀. Jesu bi í pé, “Kí ni o fẹ́?” Ó ní, “Gbà pé kí àwọn ọmọ mi mejeeji yìí jókòó pẹlu rẹ ní ìjọba rẹ, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún ekeji ní ọwọ́ òsì.” Jesu dáhùn pé, “Ẹ kò mọ ohun tí ẹ̀ ń bèèrè. Ẹ lè mu ninu ife ìrora tí èmi yóo mu?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “A lè mu ún.” Ó sọ fún wọn pé, “Lódodo ẹ óo mu ninu ife mi, ṣugbọn láti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi ati ní ọwọ́ òsì mi kò sí ní ìkáwọ́ mi láti fi fún ẹnikẹ́ni, ipò wọnyi wà fún àwọn tí a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún láti ọ̀dọ̀ Baba mi.” Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá yòókù gbọ́, inú wọn ru sí àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meji yìí. Ṣugbọn Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀, ó ní, “Ẹ mọ̀ pé àwọn aláṣẹ láàrin àwọn alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn, àwọn eniyan ńláńlá láàrin wọn a sì máa lo agbára lórí wọn. Tiyín kò ní rí bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ pataki ninu yín níláti jẹ́ iranṣẹ yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ aṣaaju yóo ṣe ẹrú fun yín. Nítorí Ọmọ-Eniyan kò wá pé kí eniyan ṣe iranṣẹ fún un; ó wá láti ṣe iranṣẹ ni, ati láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọpọlọpọ eniyan.”
Mat 20:20-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sebede bá àwọn ọmọ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jesu, ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, o béèrè fún ojúrere rẹ̀. Jesu béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?” Ó sì dáhùn pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ mi méjèèjì jókòó ní apá ọ̀tún àti apá òsì lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ?” Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn ó sì wí pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohun tí ẹ̀yin ń béèrè, ẹ̀yin ha le mu nínú ago tí èmi ó mu?” Wọ́n dáhùn pé, “Àwa lè mu ún.” Jesu sì wí fún wọn pé, “Dájúdájú, ẹ̀yin yóò mu nínú ago mi, ṣùgbọ́n èmi kò ní àṣẹ láti sọ irú ènìyàn tí yóò jókòó ní apá ọ̀tún tàbí apá òsì. Baba mi ti pèsè ààyè wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ fún kìkì àwọn tí ó yàn.” Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá ìyókù sì gbọ́ èyí, wọ́n bínú sí àwọn arákùnrin méjì yìí. Ṣùgbọ́n Jesu pé wọ́n papọ̀, ó wí pé, “Dájúdájú, ẹ̀yin mọ̀ pé àwọn ọba aláìkọlà a máa lo agbára lórí wọn, àwọn ẹni ńlá láàrín wọn a sì máa fi ọlá tẹrí àwọn tí ó wà lábẹ́ wọn ba. Ṣùgbọ́n èyí yàtọ̀ láàrín yín. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó bá ń fẹ́ ṣe olórí láàrín yín, ní láti ṣe bí ìránṣẹ́ fún yín ni, Àti ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe olórí nínú yín, ẹ jẹ́ kí ó máa ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ yin. Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ènìyàn kò ṣe wá sí ayé, kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, ṣùgbọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún yín, àti láti fi ẹ̀mí rẹ ṣe ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.”