Mat 20:20-22
Mat 20:20-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni iya awọn ọmọ Sebede ba awọn ọmọ rẹ̀ tọ̀ ọ wá, o bẹ̀ ẹ, o si nfẹ ohun kan li ọwọ́ rẹ̀. O si bi i pe, Kini iwọ nfẹ? O wi fun u pe, Jẹ ki awọn ọmọ mi mejeji ki o mã joko, ọkan li ọwọ́ ọtún rẹ, ọkan li ọwọ́ òsi ni ijọba rẹ. Ṣugbọn Jesu dahùn, o si wipe, Ẹnyin ko mọ̀ ohun ti ẹnyin mbère. Ẹnyin le mu ninu ago ti emi ó mu, ati ki a fi baptismu ti a o fi baptisi mi baptisi nyin? Nwọn wi fun u pe, Awa le ṣe e.
Mat 20:20-22 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sebede wá sọ́dọ̀ Jesu pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀. Ó kúnlẹ̀, ó ń bèèrè nǹkankan lọ́dọ̀ rẹ̀. Jesu bi í pé, “Kí ni o fẹ́?” Ó ní, “Gbà pé kí àwọn ọmọ mi mejeeji yìí jókòó pẹlu rẹ ní ìjọba rẹ, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún ekeji ní ọwọ́ òsì.” Jesu dáhùn pé, “Ẹ kò mọ ohun tí ẹ̀ ń bèèrè. Ẹ lè mu ninu ife ìrora tí èmi yóo mu?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “A lè mu ún.”
Mat 20:20-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sebede bá àwọn ọmọ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jesu, ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, o béèrè fún ojúrere rẹ̀. Jesu béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?” Ó sì dáhùn pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ mi méjèèjì jókòó ní apá ọ̀tún àti apá òsì lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ?” Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn ó sì wí pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohun tí ẹ̀yin ń béèrè, ẹ̀yin ha le mu nínú ago tí èmi ó mu?” Wọ́n dáhùn pé, “Àwa lè mu ún.”