Mat 20:17-19
Mat 20:17-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu si ngoke lọ si Jerusalemu, o si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejila si apakan li ọ̀na, o si wi fun wọn pe, Wò o, awa ngoke lọ si Jerusalemu; a o si fi Ọmọ-enia le awọn olori alufa, ati awọn akọwe lọwọ, nwọn o si da a lẹbi ikú. Nwọn o si fà a le awọn keferi lọwọ lati fi i ṣe ẹlẹyà, lati nà a, ati lati kàn a mọ agbelebu: ni ijọ kẹta yio si jinde.
Mat 20:17-19 Yoruba Bible (YCE)
Bí Jesu ti ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, ní ọ̀nà, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila sí apá kan, níkọ̀kọ̀, ó sọ fún wọn pé, “Lílọ ni à ń lọ sí Jerusalẹmu yìí o, wọn óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin lọ́wọ́, wọn óo sì dá a lẹ́bi ikú. Wọn óo fà á lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà, láti nà ati láti kàn mọ́ agbelebu. Ṣugbọn ní ọjọ́ kẹta a óo jí i dìde.”
Mat 20:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí Jesu ti ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí apá kan ó sì wí pé, “Wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Ó sọ fún wọn pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá mi lẹ́bi ikú. Wọn yóò sì fà á lé àwọn kèfèrí lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà àti láti nàa án, àti láti kàn mi mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta, yóò jí dìde.”