Mat 20:14-16
Mat 20:14-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbà eyi ti iṣe tirẹ, ki o si ma ba tirẹ lọ: emi o si fifun ikẹhin yi, gẹgẹ bi mo ti fifun ọ. Kò ha tọ́ ki emi ki o fi nkan ti iṣe ti emi ṣe bi o ti wù mi? oju rẹ korò nitoriti emi ṣe ẹni rere? Bẹ̃li awọn ikẹhin yio di ti iwaju, awọn ẹni iwaju yio si di ti ikẹhin: nitori ọ̀pọlọpọ li a pè, ṣugbọn diẹ li a o ri yàn.
Mat 20:14-16 Yoruba Bible (YCE)
Gba ohun tí ó tọ́ sí ọ kí o máa bá tìrẹ lọ; nítorí ó wù mí láti fún àwọn yìí tí wọ́n dé kẹ́yìn yìí ní ohun tí mo fún ọ. Àbí n kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ohun ìní mi bí mo ti fẹ́? Ṣé ò ń jowú nítorí mo ní inú rere ni?’ “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, àwọn èrò ẹ̀yìn yóo di ará iwájú, àwọn ará iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn.”
Mat 20:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó ní, Gba èyí tí í ṣé tìrẹ, ki ó sì máa lọ. Èmi fẹ́ láti fún ẹni ìkẹyìn gẹ́gẹ́ bí mo ti fi fún ọ. Àbí ó lòdì sí òfin pé kí èmi fún ẹnikẹ́ni ní owó mi bí mo bá yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ni ìdí tí ìwọ ní láti bínú nítorí èmi ṣe ohun rere?’ “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹni ìkẹyìn yóò di ẹni ìṣáájú, ẹni ìṣáájú yóò sì di ẹni ìkẹyìn.”