Mat 20:1-7
Mat 20:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
IJỌBA ọrun sá dabi ọkunrin kan ti iṣe bãle ile, ti o jade ni kutukutu owurọ lati pè awọn alagbaṣe sinu ọgba ajara rẹ̀. Nigbati o si ba awọn alagbaṣe pinnu rẹ̀ si owo idẹ kọkan li õjọ, o rán wọn lọ sinu ọgba ajara rẹ̀. O si jade lakokò wakati ẹkẹta ọjọ, o ri awọn alairiṣe miran, nwọn duro nibi ọja, O si wi fun wọn pe; Ẹ lọ si ọgba ajara pẹlu, ohunkohun ti o ba tọ́ emi o fifun nyin. Nwọn si mu ọ̀na wọn pọ̀n lọ sibẹ̀. O tún jade lọ lakokò wakati kẹfa ati kẹsan ọjọ, o si ṣe bẹ̃. O si jade lọ lakokò wakati kọkanla ọjọ, o ri awọn alairiṣe miran ti o duro, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi duro lati onimoni li airiṣe? Nwọn wi fun u pe, Nitoriti kò si ẹni ti o fun wa li agbaṣe; O wi fun wọn pe, Ẹ lọ pẹlu sinu ọgba ajara; eyi ti o ba tọ́ li ẹnyin o ri gbà.
Mat 20:1-7 Yoruba Bible (YCE)
“Ìjọba ọ̀run dàbí baálé ilé kan tí ó jáde ní òwúrọ̀ kutukutu láti lọ wá àwọn òṣìṣẹ́ sinu ọgbà àjàrà rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti gbà láti fún àwọn òṣìṣẹ́ náà ní owó fadaka kan fún iṣẹ́ ojúmọ́, ó ní kí wọ́n lọ ṣiṣẹ́ ninu ọgbà àjàrà òun. Ó tún jáde lọ ní agogo mẹsan-an òwúrọ̀, ó rí àwọn mìíràn tí wọn dúró ní ọjà láìṣe nǹkankan. Ó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ lọ sinu ọgbà àjàrà mi, n óo sì fun yín ní ohun tí ó bá tọ́.’ Wọ́n bá lọ. Ọkunrin náà tún jáde lọ ní agogo mejila ọ̀sán ati ní agogo mẹta ọ̀sán, ó tún ṣe bákan náà. Nígbà tí ó jáde ní agogo marun-un ìrọ̀lẹ́, ó rí àwọn mìíràn tí wọn dúró, ó bi wọ́n pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi dúró láti àárọ̀ láìṣe nǹkankan?’ Wọ́n dá a lóhùn pé, ‘Nítorí ẹnikẹ́ni kò gbà wá síṣẹ́ ni.’ Ó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ lọ sinu ọgbà àjàrà mi.’
Mat 20:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nítorí ìjọba ọ̀run dàbí ọkùnrin tí ó jẹ́ baálé kan, tí ó jíjáde lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, tí ó gba àwọn alágbàṣe sínú ọgbà àjàrà rẹ̀. Òun pinnu láti san dínárì kan fún iṣẹ́ òòjọ́ kan. Lẹ́yìn èyí ó sì rán wọn lọ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀. “Ní wákàtí kẹta ọjọ́ bí ó ti ń kọjá níwájú ilé ìgbanisíṣẹ́, ó rí díẹ̀ nínú àwọn aláìríṣẹ́ tí wọ́n dúró ní ọjà. Ó wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin pàápàá, ẹ lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà mi, bí ó bá sì di òpin ọjọ́, èmi yóò san iye ti ó bá yẹ fún yín.’ Wọ́n sì lọ. “Ó tún jáde lọ́sàn án ní nǹkan bí wákàtí kẹfà àti wákàtí kẹsànán, ó túnṣe bákan náà. Lọ́jọ́ kan náà ní wákàtí kọkànlá ọjọ́, ó tún jáde sí àárín ìlú, ó sì rí àwọn aláìríṣẹ́ mìíràn tí wọ́n dúró. Ó bi wọ́n pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kì í ṣiṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́?’ “Wọ́n sì dáhùn pé, ‘Nítorí pé kò sí ẹni tí yóò fún wa ní iṣẹ́ ṣe.’ “Ó tún sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ jáde lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú nínú ọgbà àjàrà mi.’