Mat 20:1-12

Mat 20:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)

IJỌBA ọrun sá dabi ọkunrin kan ti iṣe bãle ile, ti o jade ni kutukutu owurọ lati pè awọn alagbaṣe sinu ọgba ajara rẹ̀. Nigbati o si ba awọn alagbaṣe pinnu rẹ̀ si owo idẹ kọkan li õjọ, o rán wọn lọ sinu ọgba ajara rẹ̀. O si jade lakokò wakati ẹkẹta ọjọ, o ri awọn alairiṣe miran, nwọn duro nibi ọja, O si wi fun wọn pe; Ẹ lọ si ọgba ajara pẹlu, ohunkohun ti o ba tọ́ emi o fifun nyin. Nwọn si mu ọ̀na wọn pọ̀n lọ sibẹ̀. O tún jade lọ lakokò wakati kẹfa ati kẹsan ọjọ, o si ṣe bẹ̃. O si jade lọ lakokò wakati kọkanla ọjọ, o ri awọn alairiṣe miran ti o duro, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi duro lati onimoni li airiṣe? Nwọn wi fun u pe, Nitoriti kò si ẹni ti o fun wa li agbaṣe; O wi fun wọn pe, Ẹ lọ pẹlu sinu ọgba ajara; eyi ti o ba tọ́ li ẹnyin o ri gbà. Nigbati o di oju alẹ oluwa ọgba ajara wi fun iriju rẹ̀ pe, Pè awọn alagbaṣe nì, ki o si fi owo agbaṣe wọn fun wọn, bẹ̀rẹ lati ẹni ikẹhin lọ si ti iṣaju. Nigbati awọn ti a pè lakokò wakati kọkanla ọjọ de, gbogbo wọn gbà owo idẹ kọkan. Ṣugbọn nigbati awọn ti o ti ṣaju de, nwọn ṣebi awọn o gbà jù bẹ̃ lọ; olukuluku wọn si gbà owo idẹ kọkan. Nigbati nwọn gbà a tan, nwọn nkùn si bãle na, Wipe, Awọn ará ikẹhin wọnyi ṣiṣẹ kìki wakati kan, iwọ si mu wọn bá wa dọgba, awa ti o ti rù ẹrù, ti a si faradà õru ọjọ.

Mat 20:1-12 Yoruba Bible (YCE)

“Ìjọba ọ̀run dàbí baálé ilé kan tí ó jáde ní òwúrọ̀ kutukutu láti lọ wá àwọn òṣìṣẹ́ sinu ọgbà àjàrà rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti gbà láti fún àwọn òṣìṣẹ́ náà ní owó fadaka kan fún iṣẹ́ ojúmọ́, ó ní kí wọ́n lọ ṣiṣẹ́ ninu ọgbà àjàrà òun. Ó tún jáde lọ ní agogo mẹsan-an òwúrọ̀, ó rí àwọn mìíràn tí wọn dúró ní ọjà láìṣe nǹkankan. Ó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ lọ sinu ọgbà àjàrà mi, n óo sì fun yín ní ohun tí ó bá tọ́.’ Wọ́n bá lọ. Ọkunrin náà tún jáde lọ ní agogo mejila ọ̀sán ati ní agogo mẹta ọ̀sán, ó tún ṣe bákan náà. Nígbà tí ó jáde ní agogo marun-un ìrọ̀lẹ́, ó rí àwọn mìíràn tí wọn dúró, ó bi wọ́n pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi dúró láti àárọ̀ láìṣe nǹkankan?’ Wọ́n dá a lóhùn pé, ‘Nítorí ẹnikẹ́ni kò gbà wá síṣẹ́ ni.’ Ó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ lọ sinu ọgbà àjàrà mi.’ “Nígbà tí ọjọ́ rọ̀, ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà náà sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́, kí o fún wọn ní owó wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ó dé gbẹ̀yìn, títí dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ó kọ́kọ́ dé.’ Nígbà tí àwọn tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní agogo marun-un ìrọ̀lẹ́ dé, wọ́n gba owó fadaka kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí àwọn tí wọn kọ́kọ́ dé ibi iṣẹ́ dé, wọ́n rò pé wọn yóo gbà ju owó fadaka kọ̀ọ̀kan lọ. Ṣugbọn owó fadaka kọ̀ọ̀kan ni àwọn náà gbà. Nígbà tí wọ́n gbà á tán, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí ọlọ́gbà àjàrà náà. Wọ́n ní, ‘Wakati kan péré ni àwọn yìí tí wọ́n dé kẹ́yìn ṣe; o wá san iye kan náà fún àwa ati àwọn, àwa tí a ṣe iṣẹ́ àṣelàágùn ninu oòrùn gangan!’

Mat 20:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Nítorí ìjọba ọ̀run dàbí ọkùnrin tí ó jẹ́ baálé kan, tí ó jíjáde lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, tí ó gba àwọn alágbàṣe sínú ọgbà àjàrà rẹ̀. Òun pinnu láti san dínárì kan fún iṣẹ́ òòjọ́ kan. Lẹ́yìn èyí ó sì rán wọn lọ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀. “Ní wákàtí kẹta ọjọ́ bí ó ti ń kọjá níwájú ilé ìgbanisíṣẹ́, ó rí díẹ̀ nínú àwọn aláìríṣẹ́ tí wọ́n dúró ní ọjà. Ó wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin pàápàá, ẹ lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà mi, bí ó bá sì di òpin ọjọ́, èmi yóò san iye ti ó bá yẹ fún yín.’ Wọ́n sì lọ. “Ó tún jáde lọ́sàn án ní nǹkan bí wákàtí kẹfà àti wákàtí kẹsànán, ó túnṣe bákan náà. Lọ́jọ́ kan náà ní wákàtí kọkànlá ọjọ́, ó tún jáde sí àárín ìlú, ó sì rí àwọn aláìríṣẹ́ mìíràn tí wọ́n dúró. Ó bi wọ́n pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kì í ṣiṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́?’ “Wọ́n sì dáhùn pé, ‘Nítorí pé kò sí ẹni tí yóò fún wa ní iṣẹ́ ṣe.’ “Ó tún sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ jáde lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú nínú ọgbà àjàrà mi.’ “Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ẹni tó ni ọgbà àjàrà sọ fún aṣojú rẹ̀ pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́ náà, kí ó san owó iṣẹ́ wọn fún wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ẹni ìkẹyìn lọ sí ti ìṣáájú.’ “Nígbà tí àwọn ti a pè ní wákàtí kọkànlá ọjọ́ dé, ẹnìkọ̀ọ̀kan gba owó dínárì kan. Nígbà tí àwọn tí a gbà ṣiṣẹ́ lákọ̀ọ́kọ́ fẹ́ gba owó tiwọn, èrò wọn ni pé àwọn yóò gba jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gba owó dínárì kan. Bí wọ́n ti ń gbà á, wọ́n ń kùn sí onílẹ̀ náà, pé, ‘Wákàtí kan péré ni àwọn tí a gbà kẹ́yìn fi ṣiṣẹ́, ìwọ sì san iye kan náà fún wọn àti àwa náà ti a fi gbogbo ọjọ́ ṣiṣẹ́ nínú oòrùn gangan.’