Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Mat 2:7-8YBCV(Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Herodu pè awọn amoye na si ìkọkọ, o sì bi wọn lẹsọlẹsọ akokò ti irawọ na hàn. O si rán wọn lọ si Betlehemu, o wipe, Ẹ lọ íwadi ti ọmọ-ọwọ na lẹsọlẹsọ; nigbati ẹnyin ba si ri i, ẹ pada wá isọ fun mi, ki emi ki o le wá iforibalẹ fun u pẹlu.
Mat 2:7-8BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Herodu ọba pe àwọn amòye náà sí ìkọ̀kọ̀, ó sì wádìí ni ọwọ́ wọn, àkókò náà gan an tí wọ́n kọ́kọ́ rí ìràwọ̀. Ó sì rán wọn lọ sí Bẹtilẹhẹmu, ó sì wí pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí fínní fínní ní ti ọmọ náà tí a bí. Lẹ́yìn tí ẹ bá sì rí i, ẹ padà wá sọ fún mi, kí èmi náà le lọ foríbalẹ̀ fún un.”
Mat 2:7-8YCE(Yoruba Bible)
Hẹrọdu bá pe àwọn amòye náà síkọ̀kọ̀, ó fọgbọ́n wádìí àkókò tí ìràwọ̀ náà yọ lọ́dọ̀ wọn. Ó bá rán wọn lọ sí Bẹtilẹhẹmu. Ó ní, “Ẹ lọ, kí ẹ fẹ̀sọ̀ wádìí nípa ọmọ náà. Nígbà tí ẹ bá rí i, ẹ wá ròyìn fún mi kí èmi náà lè lọ júbà rẹ̀.”