Mat 2:19-23
Mat 2:19-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati Herodu si kú, kiyesi i, angẹli Oluwa kan yọ si Josefu li oju alá ni Egipti, Wipe, Dide, mu ọmọ-ọwọ na, ati iya rẹ̀, ki o si lọ si ilẹ Israeli: nitori awọn ti nwá ẹmí ọmọ-ọwọ na lati pa ti kú. O si dide, o mu ọmọ-ọwọ na ati iya rẹ̀, o si wá si ilẹ Israeli. Ṣugbọn nigbati o gbọ́ pe Arkelau jọba ni Judea ni ipò Herodu baba rẹ̀, o bẹ̀ru lati lọ sibẹ̀; bi Ọlọrun si ti kìlọ fun u li oju alá, o yipada si apa Galili. Nigbati o si wá, o joko ni ilu kan ti a npè ni Nasareti; ki eyi ti a ti sọ li ẹnu woli ki o le ṣẹ, pe, A o pè e ni ará Nasareti.
Mat 2:19-23 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn tí Hẹrọdu ti kú, angẹli Oluwa kan fara han Josẹfu ní ojú àlá ní Ijipti. Ó sọ fún un pé, “Dìde, gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ́, kí o pada lọ sí ilẹ̀ Israẹli, nítorí àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọmọ náà ti kú.” Josẹfu bá dìde, ó gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀ pada sí ilẹ̀ Israẹli. Nígbà tí Josẹfu gbọ́ pé Akelau ni ó jọba ní Judia ní ipò Hẹrọdu baba rẹ̀, ẹ̀rù bà á láti lọ sibẹ. Lẹ́yìn tí a ti kìlọ̀ fún un lójú àlá, ó yẹra níbẹ̀ lọ sí agbègbè Galili. Ó bá ń gbé ìlú kan tí à ń pé ní Nasarẹti. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii sọ lè ṣẹ pé, “A óo pè é ní ará Nasarẹti.”
Mat 2:19-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ikú Herodu, angẹli Olúwa fi ara hàn Josẹfu lójú àlá ní Ejibiti Ó sì wí fún un pé, “Dìde gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ padà sí ilẹ̀ Israẹli, nítorí àwọn tí ń wá ẹ̀mí ọmọ ọwọ́ náà láti pa ti kú.” Nítorí náà, o sì dìde, ó gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ó sì wá sí ilẹ̀ Israẹli. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó gbọ́ pé Akelausi ni ó ń jẹ ọba ní Judea ní ipò Herodu baba rẹ̀, ó bẹ̀rù láti lọ sí ì bẹ̀. Nítorí tí Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún un ní ojú àlá, ó yí padà, ó sì gba ẹkùn Galili lọ, ó sì lọ í gbé ní ìlú tí a pè ní Nasareti. Nígbà náà ni èyí tí a sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì wá sí ìmúṣẹ: “A ó pè é ní ará Nasareti.”