Mat 2:11-15
Mat 2:11-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati nwọn si wọ̀ ile, nwọn ri ọmọ-ọwọ na pẹlu Maria iya rẹ̀, nwọn wolẹ, nwọn si foribalẹ fun u: nigbati nwọn si tú iṣura wọn, nwọn ta a lọrẹ wura, ati turari, ati ojia. Bi Ọlọrun ti kìlọ fun wọn li oju alá pe, ki nwọn ki o máṣe pada tọ̀ Herodu lọ mọ́, nwọn gbà ọ̀na miran lọ si ilu wọn. Nigbati nwọn si ti lọ, kiyesi i, angẹli Oluwa yọ si Josefu li oju alá, o wipe, Dide gbé ọmọ-ọwọ na pẹlu iya rẹ̀, ki o si sálọ si Egipti, ki iwọ ki o si gbé ibẹ̀ titi emi o fi sọ fun ọ; nitori Herodu yio wá ọmọ-ọwọ na lati pa a. Nigbati o si dide, o mu ọmọ-ọwọ na ati iya rẹ̀ li oru, o si lọ si Egipti; O si wà nibẹ̀ titi o fi di igba ikú Herodu; ki eyi ti Oluwa wi lati ẹnu woli nì ki o le ṣẹ, pe, Ni Egipti ni mo ti pè ọmọ mi jade wá.
Mat 2:11-15 Yoruba Bible (YCE)
Bí wọ́n ti wọlé, wọ́n rí ọmọ náà pẹlu Maria ìyá rẹ̀, wọ́n kúnlẹ̀, wọ́n sì júbà rẹ̀. Wọ́n ṣí àpótí ìṣúra wọn, wọ́n fún un ní ẹ̀bùn: wúrà, turari ati òjíá. Nítorí pé Ọlọrun ti kìlọ̀ fún wọn tẹ́lẹ̀ ní ojú àlá, wọn kò pada sọ́dọ̀ Hẹrọdu mọ́; ọ̀nà mìíràn ni wọ́n gbà pada lọ sí ìlú wọn. Lẹ́yìn tí àwọn amòye ti pada lọ, angẹli Oluwa kan fara han Josẹfu ní ojú àlá, ó sọ fún un pé, “Dìde, gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀, kí o sálọ sí Ijipti, kí o sì wà níbẹ̀ títí di ìgbà tí mo bá sọ fún ọ, nítorí Hẹrọdu yóo máa wá ọmọ náà láti pa á.” Josẹfu bá dìde ní òru, ó gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀, ó lọ sí Ijipti. Níbẹ̀ ni ó wà títí Hẹrọdu fi kú. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àsọtẹ́lẹ̀ nì lè ṣẹ pé, “Láti Ijipti ni mo ti pe ọmọ mi.”
Mat 2:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí wọ́n tí wọ inú ilé náà, wọn rí ọmọ ọwọ́ náà pẹ̀lú Maria ìyá rẹ̀, wọ́n wólẹ̀, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Nígbà náà ni wọ́n tú ìṣúra wọn, wọ́n sì ta Jesu lọ́rẹ: wúrà, tùràrí àti òjìá. Nítorí pé Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún wọn ní ojú àlá pé kí wọ́n má ṣe padà tọ Herodu lọ mọ́, wọ́n gba ọ̀nà mìíràn lọ sí ìlú wọn. Nígbà tí wọn ti lọ, angẹli Olúwa fi ara hàn Josẹfu ní ojú àlá pé, “Dìde, gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀, kí ó sì sálọ sí Ejibiti. Dúró níbẹ̀ títí tí èmi yóò fi sọ fún ọ, nítorí Herodu yóò wá ọ̀nà láti pa ọmọ ọwọ́ náà.” Nígbà náà ni ó sì dìde, ó mú ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ní òru, ó sì lọ sí Ejibiti, ó sì wà níbẹ̀ títí tí Herodu fi kú. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí Olúwa sọ láti ẹnu wòlíì pé: “Mo pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.”