Mat 19:21-24 - Compare All Versions
Mat 19:21-24 YBCV (Bibeli Mimọ)
Jesu wi fun u pe, Bi iwọ ba nfẹ pé, lọ tà ohun ti o ni, ki o si fi tọrẹ fun awọn talakà, iwọ o si ni iṣura li ọrun: si wá ki o mã tọ̀ mi lẹhin. Ṣugbọn nigbati ọmọdekunrin na gbọ́ ọ̀rọ na, o jade lọ pẹlu ibanujẹ: nitoriti o li ọrọ̀ pupọ̀. Nigbana ni Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, o ṣoro gidigidi fun ọlọrọ̀ lati wọ ijọba ọrun. Mo si wi fun nyin ẹ̀wẹ, O rọrun fun ibakasiẹ lati wọ̀ oju abẹrẹ, jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ.
Mat 19:21-24 YCE (Yoruba Bible)
Jesu sọ fún un pé, “Bí o bá fẹ́ ṣe àṣepé, lọ ta dúkìá rẹ, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka; o óo sì ní ìṣúra ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, máa tẹ̀lé mi.” Nígbà tí ọdọmọkunrin náà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó kúrò níbẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́ nítorí ó ní ọrọ̀ pupọ. Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba ọ̀run. Mo tún ń wí fun yín pé yóo rọrùn fún ràkúnmí láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun lọ.”
Mat 19:21-24 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jesu wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà gbọ́ èyí, ó kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ púpọ̀. Nígbà náà, ní Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọ̀run.” Mo tún wí fún yín pé, “Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run.”