Mat 19:20-22
Mat 19:20-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọmọdekunrin na wi fun u pe, Gbogbo nkan wọnyi ni mo ti pamọ́ lati igba ewe mi wá: kili o kù mi kù? Jesu wi fun u pe, Bi iwọ ba nfẹ pé, lọ tà ohun ti o ni, ki o si fi tọrẹ fun awọn talakà, iwọ o si ni iṣura li ọrun: si wá ki o mã tọ̀ mi lẹhin. Ṣugbọn nigbati ọmọdekunrin na gbọ́ ọ̀rọ na, o jade lọ pẹlu ibanujẹ: nitoriti o li ọrọ̀ pupọ̀.
Mat 19:20-22 Yoruba Bible (YCE)
Ọdọmọkunrin náà sọ fún Jesu pé, “Gbogbo òfin wọnyi ni mo ti pamọ́. Kí ni ó tún kù kí n ṣe?” Jesu sọ fún un pé, “Bí o bá fẹ́ ṣe àṣepé, lọ ta dúkìá rẹ, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka; o óo sì ní ìṣúra ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, máa tẹ̀lé mi.” Nígbà tí ọdọmọkunrin náà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó kúrò níbẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́ nítorí ó ní ọrọ̀ pupọ.
Mat 19:20-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọmọdékùnrin náà tún wí pé, “Gbogbo òfin wọ̀nyí ni èmi ti ń pamọ́, kí ni nǹkan mìíràn tí èmi ní láti ṣe?” Jesu wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà gbọ́ èyí, ó kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.