Mat 19:18-19
Mat 19:18-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
O bi i lẽre pe, Ewo? Jesu wipe, Iwọ kò gbọdọ pa enia; Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga; Iwọ kò gbọdọ jale; Iwọ kò gbọdọ jẹri eke; Bọwọ fun baba on iya rẹ; ati ki iwọ fẹ aladugbo rẹ bi ara rẹ.
Pín
Kà Mat 19Mat 19:18-19 Yoruba Bible (YCE)
Ó bi Jesu pé, “Òfin bí irú èwo?” Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ pa eniyan. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè. Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè. Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké. Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ. Ati pé, fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.”
Pín
Kà Mat 19Mat 19:18-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọkùnrin náà béèrè pé, “Àwọn wo ni òfin wọ̀nyí?” Jesu dáhùn pé, “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn; Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà; Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè; Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké’, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ. ‘Kí o sì fẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ ”
Pín
Kà Mat 19