Mat 19:13-15
Mat 19:13-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana li a gbé awọn ọmọ-ọwọ wá sọdọ rẹ̀ ki o le fi ọwọ́ le wọn, ki o si gbadura: awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ba wọn wi. Ṣugbọn Jesu ni, Jọwọ awọn ọmọ kekere, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun ati wá sọdọ mi; nitori ti irú wọn ni ijọba ọrun. O si fi ọwọ́ le wọn, o si lọ kuro nibẹ̀.
Mat 19:13-15 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò yìí ni wọ́n gbé àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ Jesu, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn, kí ó sì súre fún wọn. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá àwọn tí wọn gbé wọn wá wí. Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má dí wọn lọ́nà, nítorí ti irú wọn ni ìjọba ọ̀run.” Ó bá gbé ọwọ́ lé wọn; ó sì kúrò níbẹ̀.
Mat 19:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn náà a sì gbé àwọn ọmọ ọwọ́ wá sọ́dọ̀ Jesu, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn, kí ó sì gbàdúrà fún wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá àwọn tí ó gbé wọn wá wí. Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má ṣe dá wọn lẹ́kun, nítorí irú wọn ni ìjọba ọ̀run.” Lẹ́yìn náà, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì kúrò níbẹ̀.