Mat 18:23-31
Mat 18:23-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina ni ijọba ọrun fi dabi ọba kan ti nfẹ gbà ìṣirò lọwọ awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀. Nigbati o bẹ̀rẹ si gbà iṣiro, a mu ọkan tọ̀ ọ wá, ti o jẹ ẹ li ẹgbãrun talenti. Njẹ bi ko ti ni ohun ti yio fi san a, oluwa rẹ̀ paṣẹ pe ki a tà a, ati obinrin rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ni, ki a si san gbese na. Nitorina li ọmọ-ọdọ na wolẹ o si tẹriba fun u, o nwipe, Oluwa, mu sũru fun mi, emi ó si san gbogbo rẹ̀ fun ọ. Oluwa ọmọ-ọdọ na si ṣãnu fun u, o tú u silẹ, o fi gbese na jì i. Ṣugbọn nigbati ọmọ-ọdọ na jade lọ, o si ri ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ ẹgbẹ rẹ̀, ti o jẹ ẹ li ọgọrun owo idẹ: o gbé ọwọ́ le e, o fún u li ọrùn, o wipe, San gbese ti iwọ jẹ mi. Ọmọ-ọdọ ẹgbẹ rẹ̀ kunlẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o si mbẹ̀ ẹ, wipe, Mu sũru fun mi, emi ó si san gbogbo rẹ̀ fun ọ. On kò si fẹ; o lọ, o gbé e sọ sinu tubu titi yio fi san gbese na. Nigbati awọn iranṣẹ ẹgbẹ rẹ̀ ri eyi ti a ṣe, ãnu ṣe wọn gidigidi, nwọn lọ nwọn si sọ gbogbo ohun ti a ṣe fun oluwa wọn.
Mat 18:23-31 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí pé ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ yanjú owó òwò pẹlu àwọn ẹrú rẹ̀. Nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣírò owó, wọ́n mú ẹnìkan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọ̀kẹ́ àìmọye. Kò ní ohun tí yóo fi san gbèsè yìí, nítorí náà olówó rẹ̀ pàṣẹ pé kí á ta òun ati iyawo rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó ní, kí á fi san gbèsè rẹ̀. Ẹrú náà bá dọ̀bálẹ̀, ó bẹ olówó rẹ̀ pé, ‘Ṣe sùúrù fún mi, n óo san gbogbo gbèsè mi fún ọ.’ Olówó rẹ̀ wá ṣàánú rẹ̀, ó bá dá a sílẹ̀, ó sì bùn ún ní owó tí ó yá. “Nígbà tí ẹrú náà jáde, ó rí ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan tí ó jẹ ẹ́ ní eélòó kan. Ó bá dì í mú, ó fún un lọ́rùn, ó ní; ‘San gbèsè tí o jẹ mí.’ Ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá dọ̀bálẹ̀, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Ṣe sùúrù fún mi, n óo san án fún ọ.’ Ṣugbọn kò gbà; ẹ̀wọ̀n ni ó ní kí wọ́n lọ jù ú sí títí yóo fi san gbèsè tí ó jẹ. Nígbà tí àwọn ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn pupọ, wọ́n bá lọ ro ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún olówó wọn.
Mat 18:23-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nítorí náà, ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ ṣe ìṣirò pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bí ó ti ń ṣe èyí, a mú ajigbèsè kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ẹgbàárùn-ún (10,000) tálẹ́ǹtì. Nígbà tí kò tì í ní agbára láti san án, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ pàṣẹ pé kí a ta òun àti ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní láti fi san gbèsè náà. “Nígbà náà ni ọmọ ọ̀dọ̀ náà wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ. ‘Ó bẹ̀bẹ̀ pé, mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san gbogbo rẹ̀ fún ọ.’ Nígbà náà, ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì ṣàánú fún un. Ó tú u sílẹ̀, ó sì fi gbèsè náà jì í. “Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà ti jáde lọ, ó rí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún owó idẹ, ó gbé ọwọ́ lé e, ó fún un ní ọrùn, ó wí pé, ‘san gbèsè tí o jẹ mí lójú ẹsẹ̀.’ “Ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ náà sì wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ̀, ò ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san án fún ọ.’ “Ṣùgbọ́n òun kọ̀ fún un. Ó pàṣẹ kí a mú ọkùnrin náà, kí a sì jù ú sínú túbú títí tí yóò fi san gbèsè náà tán pátápátá. Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn gidigidi, wọ́n lọ láti lọ sọ fún olúwa wọn, gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.