Mat 18:15-17
Mat 18:15-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Pẹlupẹlu bi arakunrin rẹ ba sẹ̀ ọ, lọ sọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ fun u ti iwọ tirẹ̀ meji: bi o ba gbọ́ tirẹ, iwọ mu arakunrin rẹ bọ̀ sipò. Ṣugbọn bi kò ba gbọ́ tirẹ, nigbana ni ki iwọ ki o mu ẹnikan tabi meji pẹlu ara rẹ, ki gbogbo ọ̀rọ li ẹnu ẹlẹri meji tabi mẹta ba le fi idi mulẹ. Bi o ba si kọ̀ lati gbọ́ wọn, wi fun ijọ enia Ọlọrun: bi o ba si kọ̀ lati gbọ́ ti ijọ enia Ọlọrun, jẹ ki o dabi keferi si ọ ati agbowodè.
Mat 18:15-17 Yoruba Bible (YCE)
“Bí arakunrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, tètè lọ bá a sọ̀rọ̀, ìwọ rẹ̀ meji péré. Bí ó bá gbà sí ọ lẹ́nu, o ti tún sọ ọ́ di arakunrin rẹ tòótọ́. Bí kò bá gbọ́, tún lọ bá a sọ ọ́, ìwọ ati ẹnìkan tabi ẹni meji; gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu àkọsílẹ̀ pé, ẹ̀rí ẹnu eniyan meji tabi mẹta ni a óo fi mọ òtítọ́ gbogbo ọ̀rọ̀. Bí kò bá gba tiwọn, sọ fún ìjọ. Bí kò bá gba ti ìjọ, kà á kún alaigbagbọ tabi agbowó-odè.
Mat 18:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, lọ ní ìkọ̀kọ̀ kí o sì sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un. Bí ó bá gbọ́ tìrẹ, ìwọ ti mú arákùnrin kan bọ̀ sí ipò. Ṣùgbọ́n bí òun kò bá tẹ́tí sí ọ, nígbà náà mú ẹnìkan tàbí ẹni méjì pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì tún padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, kí ọ̀rọ̀ náà bá le fi ìdí múlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta náà. Bí òun bá sì tún kọ̀ láti tẹ́tí sí wọn, nígbà náà sọ fún ìjọ ènìyàn Ọlọ́run. Bí o bá kọ̀ láti gbọ́ ti ìjọ ènìyàn Ọlọ́run, jẹ́ kí ó dàbí kèfèrí sí ọ tàbí agbowó òde.