Mat 18:1-9
Mat 18:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
LAKOKÒ na li awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ wá, nwọn bi i pe, Tali ẹniti o pọ̀ju ni ijọba ọrun? Jesu si pe ọmọ kekere kan sọdọ rẹ̀, o mu u duro larin wọn, O si wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, bikoṣepe ẹnyin ba pada, ki ẹ si dabi awọn ọmọ kekere, ẹnyin kì yio le wọle ijọba ọrun. Nitorina ẹnikẹni ti o ba rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ bi ọmọ kekere yi, on na ni yio pọ̀ju ni ijọba ọrun. Ẹniti o ba si gbà irú ọmọ kekere yi kan, li orukọ mi, o gbà mi, Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ọkan ninu awọn kekere wọnyi ti o gbà mi gbọ́ kọsẹ̀, o ya fun u ki a so ọlọ nla mọ́ ọ li ọrùn, ki a si rì i si ibú omi okun. Egbé ni fun aiye nitori ohun ikọsẹ̀! ohun ikọsẹ̀ ko le ṣe ki o ma de; ṣugbọn egbé ni fun oluwarẹ̀ na nipasẹ ẹniti ohun ikọsẹ̀ na ti wá! Bi ọwọ́ rẹ tabi ẹsẹ rẹ ba si mu ọ kọsẹ̀, ke e kuro, ki o si sọ ọ nù; o sàn fun ọ ki o ṣe akewọ, tabí akesẹ lọ sinu ìye, jù ki o li ọwọ́ meji tabi ẹsẹ meji, ki a gbé ọ jù sinu iná ainipẹkun. Bi oju rẹ ba si mu ọ kọsẹ̀, yọ ọ jade, ki o si sọ ọ nù; o sàn fun ọ ki o lọ sinu ìye li olojukan, jù ki o li oju meji, ki a gbé ọ sọ sinu iná ọrun apãdi.
Mat 18:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Ta ní ṣe pataki jùlọ ní ìjọba ọ̀run?” Jesu bá pe ọmọde kan, ó mú un dúró láàrin wọn, ó ní, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ kò bá yipada kí ẹ dàbí àwọn ọmọde, ẹ kò ní wọ ìjọba ọ̀run. Nítorí náà ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọde yìí, òun ni ó jẹ́ eniyan pataki jùlọ ní ìjọba ọ̀run. Ẹni tí ó bá gba ọ̀kan ninu irú àwọn ọmọde wọnyi ní orúkọ mi, èmi ni ó gbà. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún ọ̀kan ninu àwọn kéékèèké wọnyi tí ó gbà mí gbọ́, ó sàn fún un kí á so ọlọ ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí á sọ ọ́ sinu ibú òkun. Ìdájọ́ ńlá ń bẹ fún ayé, nítorí àwọn ohun ìkọsẹ̀. Dandan ni kí àwọn ohun ìkọsẹ̀ dé, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ohun ìkọsẹ̀ bá ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, ó gbé! “Bí ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù. Ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè pẹlu àbùkù ọwọ́ tabi ti ẹsẹ̀, jù pé kí o ní ọwọ́ meji tabi ẹsẹ̀ meji kí á sọ ọ́ sinu iná àjóòkú lọ. Bí ojú rẹ bá mú ọ kọsẹ̀ yọ ọ́ sọnù. Ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè pẹlu ojú kan jù pé kí o ní ojú meji kí á sọ ọ́ sinu iná ọ̀run àpáàdì lọ.
Mat 18:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní àkókò náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bi í léèrè pé, “Ta ni ẹni ti ó pọ̀jù ní ìjọba ọ̀run?” Jesu sì pe ọmọ kékeré kan sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀. Ó sì mú un dúró láàrín wọn. Ó wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àfi bí ẹ̀yin bá yí padà kí ẹ sì dàbí àwọn ọmọdé, ẹ̀yin kì yóò lè wọ ìjọba ọ̀run. Nítorí náà, ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọdé yìí, ni yóò pọ̀ jùlọ ní ìjọba ọ̀run. Àti pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọ kékeré bí èyí nítorí orúkọ mi, gbà mí. “Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ ṣìnà, yóò sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì rì í sí ìsàlẹ̀ ibú omi Òkun. Ègbé ni fún ayé nítorí gbogbo ohun ìkọ̀sẹ̀ rẹ̀! Ohun ìkọ̀sẹ̀ kò le ṣe kó má wà, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípasẹ̀ ẹni tí ìkọ̀sẹ̀ náà ti wá! Nítorí náà, bí ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀ rẹ yóò bá mú ọ dẹ́ṣẹ̀, gé e kúrò, kí o sì jù ú nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti wọ ìjọba ọ̀run ní akéwọ́ tàbí akésẹ̀ ju pé kí o ni ọwọ́ méjì àti ẹsẹ̀ méjì ki a sì sọ ọ́ sínú iná ayérayé. Bí ojú rẹ yóò bá sì mú kí o dẹ́ṣẹ̀, yọ ọ́ kúrò kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti lọ sínú ìyè pẹ̀lú ojú kan, ju pé kí o ní ojú méjì, kí a sì jù ọ́ sí iná ọ̀run àpáàdì.