Mat 18:1-6
Mat 18:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
LAKOKÒ na li awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ wá, nwọn bi i pe, Tali ẹniti o pọ̀ju ni ijọba ọrun? Jesu si pe ọmọ kekere kan sọdọ rẹ̀, o mu u duro larin wọn, O si wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, bikoṣepe ẹnyin ba pada, ki ẹ si dabi awọn ọmọ kekere, ẹnyin kì yio le wọle ijọba ọrun. Nitorina ẹnikẹni ti o ba rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ bi ọmọ kekere yi, on na ni yio pọ̀ju ni ijọba ọrun. Ẹniti o ba si gbà irú ọmọ kekere yi kan, li orukọ mi, o gbà mi, Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ọkan ninu awọn kekere wọnyi ti o gbà mi gbọ́ kọsẹ̀, o ya fun u ki a so ọlọ nla mọ́ ọ li ọrùn, ki a si rì i si ibú omi okun.
Mat 18:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Ta ní ṣe pataki jùlọ ní ìjọba ọ̀run?” Jesu bá pe ọmọde kan, ó mú un dúró láàrin wọn, ó ní, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ kò bá yipada kí ẹ dàbí àwọn ọmọde, ẹ kò ní wọ ìjọba ọ̀run. Nítorí náà ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọde yìí, òun ni ó jẹ́ eniyan pataki jùlọ ní ìjọba ọ̀run. Ẹni tí ó bá gba ọ̀kan ninu irú àwọn ọmọde wọnyi ní orúkọ mi, èmi ni ó gbà. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún ọ̀kan ninu àwọn kéékèèké wọnyi tí ó gbà mí gbọ́, ó sàn fún un kí á so ọlọ ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí á sọ ọ́ sinu ibú òkun.
Mat 18:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní àkókò náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bi í léèrè pé, “Ta ni ẹni ti ó pọ̀jù ní ìjọba ọ̀run?” Jesu sì pe ọmọ kékeré kan sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀. Ó sì mú un dúró láàrín wọn. Ó wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àfi bí ẹ̀yin bá yí padà kí ẹ sì dàbí àwọn ọmọdé, ẹ̀yin kì yóò lè wọ ìjọba ọ̀run. Nítorí náà, ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọdé yìí, ni yóò pọ̀ jùlọ ní ìjọba ọ̀run. Àti pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọ kékeré bí èyí nítorí orúkọ mi, gbà mí. “Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ ṣìnà, yóò sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì rì í sí ìsàlẹ̀ ibú omi Òkun.