Mat 17:22-27
Mat 17:22-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati nwọn mbẹ ni Galili, Jesu wi fun wọn pe, A o fi Ọmọ-enia le awọn enia lọwọ: Nwọn o si pa a, ni ijọ kẹta yio si jinde. Inu wọn si bajẹ gidigidi. Nigbati nwọn de Kapernaumu, awọn ti ngbà owodè tọ̀ Peteru wá, wipe, olukọ nyin ki isan owodè? O wipe, Bẹ̃ni. Nigbati o si wọ̀ ile, Jesu ṣiwaju rẹ̀, o bi i pe, Simoni, iwọ ti rò o si? lọwọ tali awọn ọba aiye ima gbà owodè? lọwọ awọn ọmọ wọn, tabi lọwọ awọn alejò? Peteru wi fun u pe, Lọwọ awọn alejò. Jesu wi fun u pe, Njẹ awọn ọmọ bọ́. Ṣugbọn ki a má bã bí wọn ninu, iwọ lọ si okun, ki o si sọ ìwọ si omi, ki o si mu ẹja ti o ba kọ́ fà soke; nigbati iwọ ba si yà a li ẹnu, iwọ o ri ṣekeli kan nibẹ̀: on ni ki o mu, ki o si fifun wọn fun temi ati tirẹ.
Mat 17:22-27 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n péjọ ní Galili Jesu sọ fún wọn pé, “A óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan lọ́wọ́, wọn yóo pa á; a óo sì jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.” Ọ̀rọ̀ yìí bà wọ́n ninu jẹ́ pupọ. Nígbà tí wọ́n dé Kapanaumu, àwọn tí ń gba owó Tẹmpili lọ sí ọ̀dọ̀ Peteru, wọ́n bi í pé, “Ṣé olùkọ́ni yín kì í san owó Tẹmpili ni?” Ó ní, “Kí ló dé? A máa san án.” Nígbà tí ó dé ilé, Jesu ló ṣáájú rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó ní, “Kí ni o rò, Simoni? Lọ́wọ́ àwọn ta ni àwọn ọba ayé ti ń gba owó-orí tabi owó-odè? Lọ́wọ́ àwọn ọmọ onílẹ̀ ni tabi lọ́wọ́ àlejò?” Peteru dáhùn pé, “Lọ́wọ́ àlejò ni.” Jesu wá sọ fún un pé, “Èyí ni pé kò kan àwọn ọmọ onílẹ̀. Sibẹ kí á má baà jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún wọn, lọ sí etí òkun, ju ìwọ̀ sí omi; ẹja kinni tí o bá fà sókè, mú un, ya ẹnu rẹ̀, o óo rí owó fadaka kan níbẹ̀. Mú un kí o fi fún wọ́n fún owó tèmi ati tìrẹ.”
Mat 17:22-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí wọ́n sì ti wà ní Galili, Jesu sọ fún wọn pé, “Láìpẹ́ yìí a ó fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́. Wọn yóò sì pa á, ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn èyí, yóò sì jí dìde sí ìyè.” Ọkàn àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì kún fún ìbànújẹ́ gidigidi. Nígbà tí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì dé Kapernaumu, àwọn agbowó òde tí ń gba owó idẹ méjì tó jẹ́ owó tẹmpili tọ Peteru wá wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ olùkọ́ yín ń san owó tẹmpili?” Peteru sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó ń san.” Nígbà tí Peteru wọ ilé láti bá Jesu sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, Jesu ni ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, Jesu bí i pé, “Kí ni ìwọ rò, Simoni? Ǹjẹ́ àwọn ọba ayé ń gba owó orí lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn tàbí lọ́wọ́ àwọn àlejò?” Peteru dáhùn pé, “Lọ́wọ́ àwọn àlejò ni.” Jesu sì tún wí pé, “Èyí jẹ́ wí pé àwọn ọmọ onílẹ̀ kì í san owó òde? Síbẹ̀síbẹ̀, àwa kò fẹ́ mú wọn bínú. Nítorí náà, ẹ lọ sí etí Òkun, kí ẹ sì sọ ìwọ̀ sí omi. Ẹ mú ẹja àkọ́kọ́ tí ẹ kọ́ fà sókè, ẹ ya ẹnu rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì rí owó idẹ kan níbẹ̀, ki ẹ fi fún wọn fún owó orí tèmi àti tirẹ̀.”