Mat 17:1-13
Mat 17:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
LẸHIN ijọ mẹfa Jesu mu Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu arakunrin rẹ̀, o si mu wọn wá sori òke giga li apakan, Ara rẹ̀ si yipada niwaju wọn; oju rẹ̀ si nràn bi õrùn; aṣọ rẹ̀ si fún, o dabi imọle. Si wo o, Mose ati Elijah yọ si wọn, nwọn mba a sọ̀rọ. Peteru si dahùn, o si wi fun Jesu pe, Oluwa, o dara fun wa lati mã gbé ihin: bi iwọ ba fẹ, awa o pa agọ́ mẹta sihin; ọkan fun ọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah. Bi o ti nwi lọwọ, wo o, awọsanma didán ṣiji bò wọn: si wo o, ohùn kan lati inu awọsanma wá, ti o wipe, Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dun si gidigidi; ẹ mã gbọ́ tirẹ̀. Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́, nwọn da oju wọn bolẹ, ẹru si bà wọn gidigidi. Jesu si wá, o fi ọwọ́ bà wọn, o si wipe, Ẹ dide, ẹ má bẹ̀ru. Nigbati nwọn si gbé oju wọn soke, nwọn kò ri ẹnikan, bikoṣe Jesu nikan. Bi nwọn si ti nti ori òke sọkalẹ, Jesu kìlọ fun wọn pe, Ẹ máṣe sọ̀rọ iran na fun ẹnikan, titi Ọmọ-enia yio fi tun jinde kuro ninu okú. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn akọwe ha fi wipe, Elijah ni yio tètekọ de? Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Lõtọ ni, Elijah yio tètekọ de, yio si mu nkan gbogbo pada si ipò. Ṣugbọn mo wi fun nyin pe, Elijah ti de na, nwọn kò si mọ̀ ọ, ṣugbọn nwọn ti ṣe ohunkohun ti o wù wọn si i. Gẹgẹ bẹ̃ na pẹlu li Ọmọ-enia yio jìya pupọ̀ lọdọ wọn. Nigbana li o yé awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Johanu Baptisti li ẹniti o nsọ̀rọ rẹ̀ fun wọn.
Mat 17:1-13 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹfa, Jesu mú Peteru ati Jakọbu ati Johanu arakunrin Jakọbu, wọ́n lọ sí orí òkè gíga kan; àwọn nìkan wà níbẹ̀. Jesu bá para dà lójú wọn. Ojú rẹ̀ wá ń tàn bí oòrùn. Aṣọ rẹ̀ mọ́ gbòò bí ọjọ́. Wọ́n wá rí Mose ati Elija tí wọn ń bá Jesu sọ̀rọ̀. Peteru bá sọ fún Jesu pé, “Oluwa, kì bá dára kí á máa gbé ìhín. Bí o bá fẹ́, èmi yóo pa àgọ́ mẹta síhìn-ín, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose ati ọ̀kan fún Elija.” Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìkùukùu kan tí ń tàn bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ohùn kan wá láti inú ìkùukùu náà wí pé, “Àyànfẹ́ ọmọ mi nìyí, inú mi dùn sí i. Ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.” Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́, wọ́n dojúbolẹ̀, ẹ̀rù sì bà wọ́n pupọ. Jesu wá sọ́dọ̀ wọn, ó fọwọ́ kàn wọ́n, ó ní, “Ẹ dìde. Ẹ má bẹ̀rù.” Nígbà tí wọ́n gbé ojú wọn sókè, wọn kò rí ẹnikẹ́ni mọ́, àfi Jesu nìkan. Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má sọ ohun tí ẹ rí fún ẹnikẹ́ni títí a óo fi jí Ọmọ-Eniyan dìde kúrò ninu òkú.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi í pé, “Kí ni ìdí rẹ̀ tí àwọn amòfin fi sọ pé Elija ni ó níláti kọ́kọ́ dé?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Òtítọ́ ni pé Elija yóo wá, yóo sì mú ohun gbogbo bọ̀ sípò. Ṣugbọn mo sọ fun yín, Elija ti dé, ṣugbọn àwọn eniyan kò mọ̀ ọ́n; ohun tí ó wù wọ́n ni wọ́n ṣe sí i. Bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ-Eniyan yóo sì jìyà lọ́wọ́ wọn.” Ó yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà náà pé nípa Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó ń sọ fún wọn.
Mat 17:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà, Jesu mú Peteru, Jakọbu àti Johanu arákùnrin rẹ̀, ó mú wọn lọ sí orí òkè gíga kan tí ó dádúró. Níbẹ̀ ara rẹ̀ yí padà níwájú wọn; Ojú rẹ̀ sì ràn bí oòrùn, aṣọ rẹ̀ sì funfun bí ìmọ́lẹ̀. Lójijì, Mose àti Elijah fi ara hàn, wọ́n sì ń bá Jesu sọ̀rọ̀. Peteru sọ fún Jesu pé, “Olúwa, jẹ́ kí a kúkú máa gbé níhìn-ín yìí. Bí ìwọ bá fẹ́, èmi yóò pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.” Bí Peteru ti sọ̀rọ̀ tán, àwọsánmọ̀ dídán ṣíji bò wọ́n, láti inú rẹ̀ ohùn kan wí pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni ti inú mi dùn sí gidigidi. Ẹ máa gbọ́ tirẹ̀!” Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbọ́ èyí, wọ́n dojúbolẹ̀. Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. Ṣùgbọ́n Jesu sì tọ̀ wọ́n wá. Ó fi ọwọ́ kàn wọ́n, ó wí pé, “Ẹ dìde, ẹ má ṣe bẹ̀rù.” Nígbà tí wọ́n sì gbé ojú wọn sókè, tí wọ́n sì wò ó, Jesu nìkan ni wọn rí. Bí wọ́n sì ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni ohun tí ẹ rí, títí Ọmọ ènìyàn yóò fi jí dìde kúrò nínú òkú.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ́ pé, “Kí ni ó fà á tí àwọn olùkọ́ òfin fi ń wí pé, Elijah ní láti kọ́ padà wá?” Jesu sì dáhùn pé, “Dájúdájú òtítọ́ ni wọ́n ń sọ. Elijah wá láti fi gbogbo nǹkan sí ipò. Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín lóòótọ́; Elijah ti dé. Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ ọ́n, ọ̀pọ̀ tilẹ̀ hu ìwà búburú sí i. Bákan náà, Ọmọ ènìyàn náà yóò jìyà lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú.” Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ̀ pé ó n sọ̀rọ̀ nípa Johanu onítẹ̀bọmi fún wọn ni.