Mat 16:2-4
Mat 16:2-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn o dahùn o si wi fun wọn pe, Nigbati ó ba di aṣalẹ, ẹnyin a wipe, Ọjọ ó dara: nitoriti oju ọrun pọ́n. Ati li owurọ̀ ẹnyin a wipe, Ọjọ kì yio dara loni, nitori ti oju ọrun pọ́n, o si ṣú dẹ̀dẹ. A! ẹnyin agabagebe, ẹnyin le mọ̀ àmi oju ọrun; ṣugbọn ẹnyin ko le mọ̀ àmi akokò wọnyi? Iran buburu ati panṣaga nfẹ àmi; a kì yio si fi àmi fun u, bikoṣe àmi ti Jona wolĩ. O si fi wọn silẹ, o kuro nibẹ.
Mat 16:2-4 Yoruba Bible (YCE)
Ó dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ọjọ́ bá rọ̀, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ojú ọjọ́ dára, nítorí ojú ọ̀run pupa.’ Ní òwúrọ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ìjì yóo jà lónìí nítorí pé ojú ọ̀run pupa, ó sì ṣú.’ Ẹ mọ ohun tí àmì ojú ọ̀run jẹ́, ṣugbọn ẹ kò mọ àwọn àmì àkókò yìí. Ìran burúkú ati oníbọkúbọ ń wá àmì; ṣugbọn a kò ní fi àmì kan fún un, àfi àmì Jona.” Ó bá fi wọ́n sílẹ̀ ó sì bá tirẹ̀ lọ.
Mat 16:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ó bá di àṣálẹ́, ẹ ó sọ pé, ‘Ìbá dára kí ojú ọ̀run pọ́n.’ Ní òwúrọ̀, ‘Ẹ̀yin yóò wí pé ọjọ́ kì yóò dára lónìí, nítorí ti ojú ọ̀run pọ́n, ó sì ṣú dẹ̀dẹ̀,’ ẹ̀yin àgàbàgebè, ẹ̀yin le sọ ààmì ojú ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò le mọ ààmì àwọn àkókò wọ̀nyí. Ìran búburú aláìgbàgbọ́ yìí ń béèrè ààmì àjèjì mélòó kàn ni ojú sánmọ̀, ṣùgbọ́n a kí yóò fún ẹnìkankan ní ààmì bí kò ṣe ààmì Jona.” Nígbà náà ni Jesu fi wọ́n sílẹ̀, ó sì bá tirẹ̀ lọ.