Mat 16:1-20

Mat 16:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

AWỌN Farisi pẹlu awọn Sadusi si wá, nwọn ndán a wò, nwọn si nfẹ ki o fi àmi hàn fun wọn lati ọrun wá. Ṣugbọn o dahùn o si wi fun wọn pe, Nigbati ó ba di aṣalẹ, ẹnyin a wipe, Ọjọ ó dara: nitoriti oju ọrun pọ́n. Ati li owurọ̀ ẹnyin a wipe, Ọjọ kì yio dara loni, nitori ti oju ọrun pọ́n, o si ṣú dẹ̀dẹ. A! ẹnyin agabagebe, ẹnyin le mọ̀ àmi oju ọrun; ṣugbọn ẹnyin ko le mọ̀ àmi akokò wọnyi? Iran buburu ati panṣaga nfẹ àmi; a kì yio si fi àmi fun u, bikoṣe àmi ti Jona wolĩ. O si fi wọn silẹ, o kuro nibẹ. Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si de apakeji, nwọn gbagbé lati mu akara lọwọ. Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ kiyesara, ki ẹ si mã sọra niti iwukara awọn Farisi ati ti awọn Sadusi. Nwọn si mbá ara wọn ṣaroye, wipe, Nitoriti awa ko mu akara lọwọ ni. Nigbati Jesu si woye, o wi fun wọn pe, Ẹnyin onigbagbọ́ kekere, ẽṣe ti ẹnyin fi mba ara nyin ṣaroye, nitoriti ẹnyin ko mu akara lọwọ? Kò iti yé nyin di isisiyi, ẹnyin kò si ranti iṣu akara marun ti ẹgbẹdọgbọn enia, ati iye agbọ̀n ti ẹnyin si kójọ. Ẹ kò si ranti iṣu akara meje ti ẹgbaji enia, ati iye agbọ̀n ti ẹnyin kójọ? Ẽha ti ṣe ti kò fi yé nyin pe, emi kò ti itori akara sọ fun nyin pe, ẹ kiyesi ara nyin niti iwukara ti awọn Farisi ati ti awọn Sadusi. Nigbana li o to yé wọn pe, ki iṣe iwukara ti akara li o wipe ki nwọn kiyesara rẹ̀, ṣugbọn ẹkọ́ ti awọn Farisi ati ti awọn Sadusi. Nigbati Jesu de igberiko Kesarea Filippi, o bi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lẽre, wipe, Tali awọn enia nfi emi Ọmọ-enia ipe? Nwọn si wi fun u pe, Omiran ní, Johanu Baptisti; omiran wipe, Elijah; awọn ẹlomiran ni, Jeremiah, tabi ọkan ninu awọn woli. O bi wọn lẽre, wipe, Ṣugbọn tali ẹnyin nfi mi pè? Simoni Peteru dahùn, wipe, Kristi, Ọmọ Ọlọrun alãye ni iwọ iṣe. Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Alabukun-fun ni iwọ Simoni Ọmọ Jona: ki iṣe ẹran ara ati ẹ̀jẹ li o sá fi eyi hàn ọ, ṣugbọn Baba mi ti mbẹ li ọrun. Emi si wi fun ọ pẹlu pe, Iwọ ni Peteru, ori apata yi li emi ó si kọ ijọ mi le; ẹnu-ọ̀na ipo-oku kì yio si le bori rẹ̀. Emi ó si fun ọ ni kọkọrọ ijọba ọrun: ohunkohun ti iwọ ba dè li aiye, a o si dè e li ọrun: ohunkohun ti iwọ ba tú li aiye, a o si tú u li ọrun. Nigbana li o kìlọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, ki nwọn ki o màṣe sọ fun ẹnikan pe, on ni Kristi na.

Mat 16:1-20 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn Farisi ati àwọn Sadusi wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n ń dán an wò, wọ́n ní kí ó fi àmì láti ọ̀run han àwọn. Ó dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ọjọ́ bá rọ̀, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ojú ọjọ́ dára, nítorí ojú ọ̀run pupa.’ Ní òwúrọ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ìjì yóo jà lónìí nítorí pé ojú ọ̀run pupa, ó sì ṣú.’ Ẹ mọ ohun tí àmì ojú ọ̀run jẹ́, ṣugbọn ẹ kò mọ àwọn àmì àkókò yìí. Ìran burúkú ati oníbọkúbọ ń wá àmì; ṣugbọn a kò ní fi àmì kan fún un, àfi àmì Jona.” Ó bá fi wọ́n sílẹ̀ ó sì bá tirẹ̀ lọ. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rékọjá sí òdìkejì òkun, wọ́n gbàgbé láti mú oúnjẹ lọ́wọ́. Jesu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ sì ṣe gáfárà fún ìwúkàrà àwọn Farisi ati àwọn Sadusi.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wí láàrin ara wọn pé, “Nítorí a kò mú oúnjẹ lọ́wọ́ wá ni ó ṣe sọ bẹ́ẹ̀.” Ṣugbọn Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi ń sọ láàrin ara yín nípa oúnjẹ tí ẹ kò ní, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré? Òye kò ì tíì ye yín sibẹ? Ẹ kò ranti burẹdi marun-un tí mo fi bọ́ ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan ati iye agbọ̀n àjẹkù tí ẹ kó jọ? Ti burẹdi meje ńkọ́, tí mo fi bọ́ ẹgbaaji (4,000) eniyan ati iye apẹ̀rẹ̀ àjẹkù tí ẹ kó jọ? Kí ló dé tí kò fi ye yín pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ oúnjẹ ni mò ń sọ? Ẹ ṣe gáfárà fún ìwúkàrà àwọn Farisi ati Sadusi.” Nígbà náà ni ó wá yé wọn pé kì í ṣe ti ìwúkàrà tí à ń fi sinu burẹdi ni ó ń sọ, ti ẹ̀kọ́ àwọn Farisi ati Sadusi ni ó ń sọ. Nígbà tí Jesu dé agbègbè ìlú Kesaria ti Filipi, ó bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ta ni àwọn eniyan rò pé Ọmọ-Eniyan jẹ́?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ní Johanu Onítẹ̀bọmi ni. Àwọn mìíràn ní Elija ni. Àwọn mìíràn tún ní Jeremaya ni tabi ọ̀kan ninu àwọn wolii.” Ó wá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ńkọ́? Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́?” Simoni Peteru dá a lóhùn pé, “Ìwọ ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun Alààyè.” Jesu sọ fún un pé, “O káre, Simoni, ọmọ Jona, nítorí kì í ṣe eniyan ni ó fi èyí hàn ọ́ bíkòṣe Baba mi tí ń bẹ lọ́run. Mo sọ fún ọ pé: Peteru ni ọ́, ní orí àpáta yìí ni n óo kọ́ ìjọ mi lé; agbára ikú kò ní lè ká a. N óo fún ọ ní kọ́kọ́rọ́ ìjọba ọ̀run. Ohunkohun tí o bá dè ní ayé, ó di dídè ní ọ̀run. Ohunkohun tí o bá sì tú ní ayé, ó di títú ní ọ̀run.” Nígbà náà ni Jesu wá pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn má sọ fún ẹnikẹ́ni pé òun ni Mesaya.

Mat 16:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn Farisi àti àwọn Sadusi wá láti dán Jesu wò. Wọ́n ní kí ó fi ààmì ńlá kan hàn àwọn ní ojú ọ̀run. Ó dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ó bá di àṣálẹ́, ẹ ó sọ pé, ‘Ìbá dára kí ojú ọ̀run pọ́n.’ Ní òwúrọ̀, ‘Ẹ̀yin yóò wí pé ọjọ́ kì yóò dára lónìí, nítorí ti ojú ọ̀run pọ́n, ó sì ṣú dẹ̀dẹ̀,’ ẹ̀yin àgàbàgebè, ẹ̀yin le sọ ààmì ojú ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò le mọ ààmì àwọn àkókò wọ̀nyí. Ìran búburú aláìgbàgbọ́ yìí ń béèrè ààmì àjèjì mélòó kàn ni ojú sánmọ̀, ṣùgbọ́n a kí yóò fún ẹnìkankan ní ààmì bí kò ṣe ààmì Jona.” Nígbà náà ni Jesu fi wọ́n sílẹ̀, ó sì bá tirẹ̀ lọ. Nígbà tí wọ́n dé apá kejì adágún, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ṣàkíyèsí pé wọ́n ti gbàgbé láti mú àkàrà kankan lọ́wọ́. Jesu sì kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ kíyèsára, ẹ sì ṣọ́ra, ní ti ìwúkàrà àwọn Farisi àti àwọn Sadusi.” Wọ́n ń sọ eléyìí ni àárín ara wọn wí pé, “Nítorí tí àwa kò mú àkàrà lọ́wọ́ ni.” Nígbà tí ó gbọ́ ohun ti wọ́n ń sọ, Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré, èéṣe tí ẹ̀yin ń dààmú ara yín pé ẹ̀yin kò mú oúnjẹ lọ́wọ́? Tàbí ọ̀rọ̀ kò yé yín di ìsinsin yìí? Ẹ̀yin kò rántí pé mo bọ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5,000) ènìyàn pẹ̀lú ìṣù àkàrà márùn-ún àti iye agbọ̀n tí ẹ kójọ bí àjẹkù? Ẹ kò sì tún rántí ìṣù méje tí mo fi bọ́ ẹgbàajì (4,000) ènìyàn àti iye agbọ̀n tí ẹ̀yín kójọ? Èéha ṣe tí kò fi yé yín pé èmi kò sọ̀rọ̀ nípa ti àkàrà? Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo wí fún yín, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisi àti ti Sadusi.” Nígbà náà ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé wọn pé, kì í ṣe nípa ti ìwúkàrà ní ó sọ wí pé kí wọ́n kíyèsára, bí kò ṣe tí ẹ̀kọ́ àwọn Farisi àti Sadusi. Nígbà tí Jesu sì dé Kesarea-Filipi, ó bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi Ọmọ ènìyàn pè?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ni Johanu onítẹ̀bọmi ni, àwọn mìíràn wí pé, Elijah ni, àwọn mìíràn wí pé, Jeremiah ni, tàbí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì.” “Ṣùgbọ́n ẹyin ń kọ?” Ó bi í léèrè pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fi mi pè?” Simoni Peteru dáhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.” Jesu sì wí fún un pé, “Alábùkún fún ni ìwọ Simoni ọmọ Jona, nítorí ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ kọ́ ló fi èyí hàn bí kò ṣe Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run. Èmi wí fún ọ, ìwọ ni Peteru àti pé orí àpáta yìí ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi lé, àti ẹnu-ọ̀nà ipò òkú kì yóò lè borí rẹ̀. Èmi yóò fún ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba Ọ̀run; Ohun tí ìwọ bá dè ní ayé, òun ni a ó dè ní ọ̀run. Ohunkóhun tí ìwọ bá sì tú ní ayé yìí, a ó sì tú ní ọ̀run.” Nígbà náà ó kìlọ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni pé Òun ni Kristi náà.