Mat 15:25-27 - Compare All Versions

Mat 15:25-27 YBCV (Bibeli Mimọ)

Nigbana li o wá, o si tẹriba fun u, wipe, Oluwa, ràn mi lọwọ. Ṣugbọn o dahùn, wipe, Ko tọ́ ki a mu akara awọn ọmọ, ki a fi i fun ajá. O si wipe, Bẹni, Oluwa: awọn ajá a ma jẹ ninu ẹrún ti o ti ori tabili oluwa wọn bọ́ silẹ.

Mat 15:25-27 YCE (Yoruba Bible)

Ṣugbọn obinrin náà wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ràn mí lọ́wọ́.” Ṣugbọn Jesu dá a lóhùn pé, “Kò dára láti sọ oúnjẹ ọmọ eniyan sóde sí àwọn ajá!” Obinrin náà ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa. Ṣugbọn àwọn ajá a máa jẹ ẹ̀ẹ́rún oúnjẹ tí ó bọ́ sílẹ̀ láti inú àwo oúnjẹ oluwa wọn.”

Mat 15:25-27 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Obìnrin náà wá, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀bẹ̀ sí i pé, “Olúwa ṣàánú fún mi.” Ó sì dáhùn wí pé, “Kò tọ́ kí a gbé oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.” Obìnrin náà sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ajá a máa jẹ èrúnrún tí ó ti orí tábìlì olówó wọn bọ́ sílẹ̀.”