Mat 15:24-26
Mat 15:24-26 Yoruba Bible (YCE)
Jesu bá dáhùn pé, “Kìkì àwọn aguntan tí ó sọnù, àní ìdílé Israẹli nìkan ni a rán mi sí.” Ṣugbọn obinrin náà wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ràn mí lọ́wọ́.” Ṣugbọn Jesu dá a lóhùn pé, “Kò dára láti sọ oúnjẹ ọmọ eniyan sóde sí àwọn ajá!”
Pín
Kà Mat 15Mat 15:24-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn o dahùn wipe, A kò rán mi, bikoṣe si awọn agutan ile Israeli ti o nù. Nigbana li o wá, o si tẹriba fun u, wipe, Oluwa, ràn mi lọwọ. Ṣugbọn o dahùn, wipe, Ko tọ́ ki a mu akara awọn ọmọ, ki a fi i fun ajá.
Pín
Kà Mat 15