Mat 14:27-29
Mat 14:27-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn lojukanna ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ tújuka; Emi ni; ẹ má bẹ̀ru. Peteru si dá a lohùn, wipe, Oluwa, bi iwọ ba ni, paṣẹ ki emi tọ̀ ọ wá lori omi. O si wipe, Wá. Nigbati Peteru sọkalẹ lati inu ọkọ̀ lọ, o rìn loju omi lati tọ̀ Jesu lọ.
Mat 14:27-29 Yoruba Bible (YCE)
Lẹsẹkẹsẹ Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣe ara gírí. Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù!” Peteru sọ fún un pé, “Oluwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni, sọ pé kí n máa rìn bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ lójú omi.” Jesu bá sọ fún un pé, “Máa bọ̀!” Ni Peteru bá sọ̀kalẹ̀ ninu ọkọ̀, ó rìn lójú omi lọ sọ́dọ̀ Jesu.
Mat 14:27-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lójúkan náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni ẹ má ṣe bẹ̀rù.” Peteru sì ké sí i pé, “Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni nítòótọ́, sọ pé kí n tọ̀ ọ́ wà lórí omi.” Jesu dá a lóhùn pé, “Ó dára, máa bọ̀ wá.” Nígbà náà ni Peteru sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀. Ó ń rìn lórí omi lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jesu.