Mat 14:26-31
Mat 14:26-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i ti o nrìn lori okun, ẹ̀ru bà wọn, nwọn wipe, Iwin ni; nwọn fi ibẹru kigbe soke. Ṣugbọn lojukanna ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ tújuka; Emi ni; ẹ má bẹ̀ru. Peteru si dá a lohùn, wipe, Oluwa, bi iwọ ba ni, paṣẹ ki emi tọ̀ ọ wá lori omi. O si wipe, Wá. Nigbati Peteru sọkalẹ lati inu ọkọ̀ lọ, o rìn loju omi lati tọ̀ Jesu lọ. Ṣugbọn nigbati o ri ti afẹfẹ le, ẹru ba a; o si bẹ̀rẹ si irì, o kigbe soke, wipe, Oluwa, gbà mi. Lojukanna Jesu si nà ọwọ́ rẹ̀, o dì i mu, o si wi fun u pe, Iwọ onigbagbọ́ kekere, ẽṣe ti iwọ fi nṣiyemeji?
Mat 14:26-31 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù bà wọ́n gan-an, wọ́n ń sọ pé, “Iwin ni!” Wọ́n bá kígbe, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n. Lẹsẹkẹsẹ Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣe ara gírí. Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù!” Peteru sọ fún un pé, “Oluwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni, sọ pé kí n máa rìn bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ lójú omi.” Jesu bá sọ fún un pé, “Máa bọ̀!” Ni Peteru bá sọ̀kalẹ̀ ninu ọkọ̀, ó rìn lójú omi lọ sọ́dọ̀ Jesu. Ṣugbọn nígbà tí ó rí i tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́, ẹ̀rù bà á, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí rì. Ó bá kígbe pé, “Oluwa, gbà mí!” Lẹsẹkẹsẹ Jesu bá fà á lọ́wọ́, ó sọ fún un pé, “Ìwọ onigbagbọ kékeré yìí! Kí ni ó mú ọ ṣe iyè meji?”
Mat 14:26-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù ba wọn gidigidi, wọ́n rò pé “iwin ni” wọ́n kígbe tìbẹ̀rù tìbẹ̀rù. Lójúkan náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni ẹ má ṣe bẹ̀rù.” Peteru sì ké sí i pé, “Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni nítòótọ́, sọ pé kí n tọ̀ ọ́ wà lórí omi.” Jesu dá a lóhùn pé, “Ó dára, máa bọ̀ wá.” Nígbà náà ni Peteru sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀. Ó ń rìn lórí omi lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jesu. Nígbà tí ó rí afẹ́fẹ́ líle, ẹ̀rù bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ó kígbe lóhùn rara pé, “Gbà mí, Olúwa.” Lójúkan náà, Jesu na ọwọ́ rẹ̀, ó dìímú, ó sì gbà á. Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣiyèméjì ìwọ onígbàgbọ́ kékeré?”