Mat 14:22-23
Mat 14:22-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lojukanna Jesu si rọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati bọ sinu ọkọ̀, ki nwọn ki o ṣiwaju rẹ̀ lọ si apakeji, nigbati on tú ijọ enia ká. Nigbati o si tú ijọ enia ká tan, o gùn ori òke lọ, on nikan, lati gbadura: nigbati alẹ si lẹ, on nikan wà nibẹ̀.
Mat 14:22-23 Yoruba Bible (YCE)
Lẹsẹkẹsẹ, ó bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn wọ ọkọ̀ ojú omi ṣáájú òun lọ sí òdìkejì, nígbà tí ó ń tú àwọn eniyan ká. Nígbà tí ó tú wọn ká tán, ó gun orí òkè lọ gbadura, òun nìkan. Nígbà tí alẹ́ lẹ́, òun nìkan ni ó wà níbẹ̀.
Mat 14:22-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n bọ sínú ọkọ̀ wọn, àti kí wọ́n máa kọjá lọ ṣáájú rẹ̀ sí òdìkejì. Òun náà dúró lẹ́yìn láti tú àwọn ènìyàn ká lọ sí ilé wọn Lẹ́yìn tí ó tú ìjọ ènìyàn ká tán, ó gun orí òkè lọ fúnrarẹ̀ láti lọ gba àdúrà. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, òun wà nìkan níbẹ̀