Mat 13:40-42
Mat 13:40-42 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina gẹgẹ bi a ti kó èpo jọ, ti a si fi iná sun wọn; bẹ̃ni yio ri ni igbẹhin aiye. Ọmọ-enia yio rán awọn angẹli rẹ̀, nwọn o si kó gbogbo ohun ti o mu-ni-kọsẹ̀ ni ijọba rẹ̀ kuro, ati awọn ti o ndẹṣẹ. Yio si sọ wọn sinu iná ileru: nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbe wà.
Mat 13:40-42 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, bí wọn tíí kó èpò jọ tí wọn ń sun ún ninu iná, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Ọmọ-Eniyan yóo rán àwọn angẹli rẹ̀, wọn yóo kó gbogbo àwọn amúni-ṣìnà ati àwọn arúfin kúrò ninu ìjọba rẹ̀. Wọn yóo sọ wọ́n sinu iná ìléru. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.
Mat 13:40-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Gẹ́gẹ́ bí a ti kó èpò jọ, tí a sì sun ún nínú iná, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Ọmọ Ènìyàn yóò ran àwọn angẹli rẹ̀, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tó ń mú ni dẹ́ṣẹ̀ kúrò ní ìjọba rẹ̀ àti gbogbo ènìyàn búburú. Wọn yóò sì sọ wọ́n sí inú iná ìléru, níbi ti ẹkún òun ìpayínkeke yóò gbé wà.