Mat 13:24-43

Mat 13:24-43 Bibeli Mimọ (YBCV)

Owe miran li o pa fun wọn, wipe: Ijọba ọrun dabi ọkunrin ti o fún irugbin rere si oko rẹ̀: Ṣugbọn nigbati enia sùn, ọtá rẹ̀ wá, o fún èpo sinu alikama, o si ba tirẹ̀ lọ. Ṣugbọn nigbati ẽhu rẹ̀ sọ jade, ti o si so eso, nigbana li èpo buburu fi ara hàn pẹlu. Bẹ̃li awọn ọmọ-ọdọ bãle na tọ̀ ọ wá, nwọn wi fun u pe, Oluwa, irugbin rere ki iwọ fún sinu oko rẹ? nibo li o ha ti li èpo buburu? O si wi fun wọn pe, Ọtá li o ṣe eyi. Awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ si bi i pe, Iwọ ha fẹ́ ki a lọ fà wọn tu kuro? O si wipe, Bẹ̃kọ, nigbati ẹnyin ba ntu èpo kuro, ki ẹnyin ki o má bà tu alikama pẹlu wọn. Ẹ jẹ ki awọn mejeji ki o dàgba pọ̀ titi di igba ikorè: li akokò ikorè emi o si wi fun awọn olukore pe, Ẹ tètekọ kó èpo jọ, ki ẹ di wọn ni ití lati fi iná sun wọn, ṣugbọn ẹ kó alikama sinu abà mi. Owe miran li o pa fun wọn, wipe, Ijọba ọrun dabi wóro irugbin mustardi kan, eyiti ọkunrin kan mu ti o si gbìn sinu oko rẹ̀: Eyiti o kére jù gbogbo irugbin lọ; ṣugbọn nigbati o dàgba, o tobi jù gbogbo ewebẹ lọ, o si di igi, tobẹ ti awọn ẹiyẹ oju ọrun si wá, nwọn ngbé ori ẹ̀ka rẹ̀. Owe miran li o pa fun wọn pe, Ijọba ọrun dabi iwukara, ti obinrin kan mu, ti o sin sinu oṣuwọn iyẹfun mẹta, titi gbogbo rẹ̀ fi di wiwu. Gbogbo nkan wọnyi ni Jesu fi powe fun awọn ijọ enia; kò si ba wọn sọ̀rọ bikoṣe li owe: Ki eyiti a ti ẹnu woli sọ ki o ba le ṣẹ, wipe, Emi ó yà ẹnu mi li owe; emi ó sọ nkan wọnni jade ti o ti fi ara pamọ́ lati iṣẹ̀dalẹ aiye wá. Nigbana ni Jesu rán ijọ enia lọ, o si wọ̀ ile; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ wá, wipe, Sọ idi owe èpo ti oko fun wa. O dahùn o si wi fun wọn pe, Ọmọ-enia li ẹniti nfunrugbin rere; Oko li aiye; irugbin rere li awọn ọmọ ijọba; èpo si li awọn ọmọ ẹni buburu ni; Ọta ti o fún wọn li Èṣu; igbẹhin aiye ni ikorè; awọn angẹli si li awọn olukore. Nitorina gẹgẹ bi a ti kó èpo jọ, ti a si fi iná sun wọn; bẹ̃ni yio ri ni igbẹhin aiye. Ọmọ-enia yio rán awọn angẹli rẹ̀, nwọn o si kó gbogbo ohun ti o mu-ni-kọsẹ̀ ni ijọba rẹ̀ kuro, ati awọn ti o ndẹṣẹ. Yio si sọ wọn sinu iná ileru: nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbe wà. Nigbana li awọn olododo yio ma ràn bi õrun ni ijọba Baba wọn. Ẹniti o ba li etí ki o gbọ́.

Mat 13:24-43 Yoruba Bible (YCE)

Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn. Ó ní, “Bí ìjọba ọ̀run ti rí nìyí. Ó dàbí ọkunrin kan tí ó gbin irúgbìn rere sí oko rẹ̀. Nígbà tí àwọn eniyan sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá, ó gbin èpò sáàrin ọkà, ó bá lọ. Nígbà tí ọkà dàgbà, tí ó yọ ọmọ, èpò náà dàgbà. Àwọn ẹrú baálé náà bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, ‘Alàgbà, ṣebí irúgbìn rere ni o gbìn sí oko, èpò ti ṣe débẹ̀?’ Ó dá wọn lóhùn pé, ‘Ọ̀tá ni ó ṣe èyí.’ Àwọn ẹrú rẹ̀ ní, ‘Ṣé kí á lọ tu wọ́n dànù?’ Ó bá dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá o! Bí ẹ bá wí pé ẹ̀ ń tu èpò, ẹ óo tu ọkà náà. Ẹ jẹ́ kí àwọn mejeeji jọ dàgbà pọ̀ títí di ìgbà ìkórè. Ní àkókò ìkórè, n óo sọ fún àwọn olùkórè pé: ẹ kọ́ kó èpò jọ, kí ẹ dì wọ́n nítìí-nítìí, kí ẹ dáná sun ún. Kí ẹ wá kó ọkà jọ sinu abà mi.’ ” Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn. Ó ní, “Báyìí ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí wóró musitadi tí ẹnìkan gbìn sinu oko rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó kéré jùlọ ninu gbogbo irúgbìn, sibẹ nígbà tí ó bá dàgbà, a tóbi ju gbogbo ewébẹ̀ lọ. A di igi, tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run óo wá ṣe ìtẹ́ wọn lára ẹ̀ka rẹ̀.” Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn. Ó ní, “Ìjọba ọ̀run dàbí ìwúkàrà tí obinrin kan mú, tí ó pò mọ́ òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun ńláńlá mẹta títí gbogbo rẹ̀ fi wú sókè.” Jesu sọ gbogbo nǹkan wọnyi fún àwọn eniyan ní òwe. Kò sọ ohunkohun fún wọn láì lo òwe; kí ọ̀rọ̀ tí wolii ti sọ lè ṣẹ, nígbà tí ó sọ pé, “Bí òwe bí òwe ni ọ̀rọ̀ mi yóo jẹ́. N óo sọ àwọn ohun tí ó ti wà ní àṣírí láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.” Nígbà tí Jesu kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan, ó lọ sinu ilé. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sọ pé, “Ṣe àlàyé òwe èpò inú oko fún wa.” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó fúnrúgbìn rere ni Ọmọ-Eniyan. Ayé ni oko tí ó fúnrúgbìn sí. Irúgbìn rere ni àwọn ọmọ ìjọba ọ̀run. Èpò ni àwọn ọmọ èṣù. Ọ̀tá tí ó fọ́n èpò ni èṣù. Ìkórè ni ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn angẹli ni olùkórè. Nítorí náà, bí wọn tíí kó èpò jọ tí wọn ń sun ún ninu iná, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Ọmọ-Eniyan yóo rán àwọn angẹli rẹ̀, wọn yóo kó gbogbo àwọn amúni-ṣìnà ati àwọn arúfin kúrò ninu ìjọba rẹ̀. Wọn yóo sọ wọ́n sinu iná ìléru. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà. Àwọn olódodo yóo wá máa ràn bí oòrùn ninu ìjọba Baba wọn. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́.

Mat 13:24-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Jesu tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí àgbẹ̀ kan tí ó gbin irúgbìn rere sí oko rẹ̀; Ṣùgbọ́n ní òru ọjọ́ kan, nígbà tí ó sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá sí oko náà ó sì gbin èpò sáàrín alikama, ó sì bá tirẹ̀ lọ. Nígbà tí alikama náà bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà, tí ó sì so èso, nígbà náà ni èpò náà fi ara hàn. “Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ àgbẹ̀ náà wá, wọ́n sọ fún un pé, ‘Ọ̀gá, irúgbìn rere kọ́ ni ìwọ ha gbìn sí oko rẹ nì? Báwo ni èpò ṣe wà níbẹ̀ nígbà náà?’ “Ó sọ fún wọn pé, ‘Ọ̀tá ni ó ṣe èyí.’ “Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tún bí i pé, ‘Ǹjẹ́ ìwọ ha fẹ́ kí a fa èpò náà tu kúrò?’ “Ó dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá, nítorí bí ẹ̀yin bá ń tu èpò kúrò, ẹ ó tu alikama dànù pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí àwọn méjèèjì máa dàgbà pọ̀, títí di àsìkò ìkórè. Èmi yóò sọ fún àwọn olùkórè náà láti kọ́kọ́ ṣa àwọn èpò kúrò kí wọ́n sì dìwọ́n ní ìtí, kí a sì sun wọn, kí wọ́n sì kó alikama sínú àká mi.’ ” Jesu tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí èso hóró musitadi, èyí tí ọkùnrin kan mú tí ó gbìn sínú oko rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ èso tí ó kéré púpọ̀ láàrín èso rẹ̀, síbẹ̀ ó wá di ohun ọ̀gbìn tí ó tóbi jọjọ. Ó sì wá di igi tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì wá, wọ́n sì fi ẹ̀ka rẹ ṣe ibùgbé.” Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí ìwúkàrà tí obìnrin kan mú tí ó pò mọ́ ìyẹ̀fun púpọ̀ títí tí gbogbo rẹ fi di wíwú.” Òwe ni Jesu fi sọ nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, òwe ni ó fi bá wọn sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tó sọ. Kí ọ̀rọ̀ tí a ti ẹnu àwọn wòlíì sọ lé wá sí ìmúṣẹ pé: “Èmi yóò ya ẹnu mi láti fi òwe sọ̀rọ̀. Èmi yóò sọ àwọn ohun tí ó fi ara sin láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá.” Lẹ́yìn náà ó sì fi ọ̀pọ̀ ènìyàn sílẹ̀ lóde, ó wọ ilé lọ. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn wí pé, “Ṣàlàyé òwe èpò inú oko fún wa.” Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ọmọ ènìyàn ni ẹni tí ó ń fúnrúgbìn rere. Ayé ni oko náà; irúgbìn rere ni àwọn ènìyàn ti ìjọba ọ̀run. Èpò ni àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ti èṣù, ọ̀tá tí ó gbin àwọn èpò sáàrín alikama ni èṣù. Ìkórè ni òpin ayé, àwọn olùkórè sì ní àwọn angẹli. “Gẹ́gẹ́ bí a ti kó èpò jọ, tí a sì sun ún nínú iná, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Ọmọ Ènìyàn yóò ran àwọn angẹli rẹ̀, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tó ń mú ni dẹ́ṣẹ̀ kúrò ní ìjọba rẹ̀ àti gbogbo ènìyàn búburú. Wọn yóò sì sọ wọ́n sí inú iná ìléru, níbi ti ẹkún òun ìpayínkeke yóò gbé wà. Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò máa ràn bí oòrùn ní ìjọba Baba wọn. Ẹni tí ó bá létí, jẹ́ kí ó gbọ́.