Mat 13:14-15
Mat 13:14-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Si ara wọn ni ọrọ̀ Isaiah wolí si ti ṣẹ, ti o wipe, Ni gbigbọ́ ẹnyin ó gbọ́, kì yio si yé nyin; ati riri ẹnyin o ri, ẹnyin kì yio si moye. Nitoriti àiya awọn enia yi sebọ, etí wọn si wuwo ọ̀ran igbọ́, oju wọn ni nwọn si dì; nitori ki nwọn ki o má ba fi oju wọn ri, ki nwọn ki o má ba fi etí wọn gbọ́, ki nwọn ki o má ba fi àiya wọn mọ̀, ki nwọn ki o má ba yipada, ki emi ki o má ba mu wọn larada.
Mat 13:14-15 Yoruba Bible (YCE)
Báyìí ni àsọtẹ́lẹ̀ Aisaya ṣe ṣẹ sí wọn lára, nígbà tí ó sọ pé. ‘Ní ti gbígbọ́, ẹ óo gbọ́, ṣugbọn kò ní ye yín; ní ti pé kí ẹ ríran, ẹ óo wò títí, ṣugbọn ẹ kò ní rí nǹkankan. Ọkàn àwọn eniyan yìí ti le, etí wọn ti di, wọ́n sì ti di ojú wọn. Kí wọn má baà fi ojú wọn ríran, kí wọn má baà fi etí wọn gbọ́ràn, kí wọn má baà mòye, kí wọn má baà yipada, kí n wá gbà wọ́n là.’
Mat 13:14-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Sí ara wọn ni a ti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Isaiah ṣẹ: “ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́ ṣùgbọ́n kì yóò sì yé yín; ní rí rí ẹ̀yin yóò rí, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò sì mòye. Nítorí àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́ etí wọn sì wúwo láti gbọ́ ojú wọn ni wọ́n sì dì nítorí kí àwọn má ba à fi ojú wọn rí kí wọ́n má ba à fi etí wọn gbọ́ kí wọn má ba à fi àyà wọn mọ̀ òye, kí wọn má ba à yípadà, kí èmi ba à le mú wọn láradá.’