Mat 13:1-3
Mat 13:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI ọjọ kanna ni Jesu ti ile jade, o si joko leti okun. Ọpọlọpọ enia pejọ sọdọ rẹ̀, tobẹ̃ ti o fi bọ sinu ọkọ̀, o joko; gbogbo enia si duro leti okun. O si fi owe ba wọn sọ̀rọ ohun pipọ, o wipe, Wo o, afunrugbin kan jade lọ lati funrugbin
Mat 13:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kan náà, Jesu jáde kúrò nílé, ó lọ jókòó létí òkun. Ọ̀pọ̀ eniyan péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wọ inú ọkọ̀ ojú omi kan. Ó jókòó níbẹ̀, àwọn eniyan bá dúró ní etí òkun. Ó sọ ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ fún wọn pẹlu òwe. Ó ní: “Ní ọjọ́ kan, afunrugbin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn.
Mat 13:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kan náà, Jesu kúrò ní ilé, ó jókòó sí etí Òkun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, ó jókòó, gbogbo ènìyàn sì dúró létí Òkun. Nígbà náà ni ó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe bá wọn sọ̀rọ̀, wí pé: “Àgbẹ̀ kan jáde lọ gbin irúgbìn sínú oko rẹ̀.