Mat 12:9-14
Mat 12:9-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o si kuro nibẹ̀, o lọ sinu sinagogu wọn. Si kiyesi i, ọkunrin kan wà nibẹ̀, ti ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Nwọn si bi i pe, O ha tọ́ lati mu-ni-larada li ọjọ isimi? ki nwọn ki o le fẹ ẹ li ẹfẹ̀. O si wi fun wọn pe, Ọkunrin wo ni iba ṣe ninu nyin, ti o li agutan kan, bi o ba si bọ́ sinu ihò li ọjọ isimi, ti ki yio dì i mu, ki o si fà a soke? Njẹ melomelo li enia san jù agutan lọ? nitorina li o ṣe tọ́ lati mã ṣe rere li ọjọ isimi. Nitorina li o wi fun ọkunrin na pe, Na ọwọ́ rẹ. On si nà a; ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò rẹ̀ gẹgẹ bi ekeji. Nigbana li awọn Farisi jade lọ, nwọn si gbìmọ nitori rẹ̀, bi awọn iba ti ṣe pa a.
Mat 12:9-14 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn èyí, Jesu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí inú ilé ìpàdé wọn. Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Wọ́n bi í pé, “Ṣé ó bá òfin mu láti ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi?” Kí wọ́n baà lè rí ẹ̀sùn fi kàn án ni wọ́n fi bèèrè ìbéèrè yìí. Ó bá bi wọ́n báyìí pé, “Ta ni ninu yín tí yóo ní aguntan kan, bí ọ̀kan náà bá jìn sí kòtò ní Ọjọ́ Ìsinmi, tí kò ní fà á jáde? Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí eniyan ti sàn ju aguntan lọ, ó tọ́ láti ṣe rere ní Ọjọ́ Ìsinmi.” Ó bá sọ fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó bá nà án. Ọwọ́ rẹ̀ bá bọ́ sípò gẹ́gẹ́ bí ekeji. Àwọn Farisi bá jáde lọ láti gbèrò nípa rẹ̀, bí wọn óo ṣe lè pa á.
Mat 12:9-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀ ó lọ sí Sinagọgu wọn, ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ wà níbẹ̀. Wọ́n ń wá ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jesu, wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti mú ènìyàn láradá ní ọjọ́ ìsinmi?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ wí pé bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ní àgùntàn kan ṣoṣo, tí ó sì bọ́ sínú kòtò ní ọjọ́ ìsinmi, ǹjẹ́ kì yóò dìímú, kí ó sì fà á jáde. Ǹjẹ́ mélòó mélòó ní ènìyàn ní iye lórí ju àgùntàn kan lọ! Nítorí náà ó yẹ láti ṣe rere ní ọjọ́ ìsinmi.” Nígbà náà, ó sì wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ,” bí òun sì ti nà án, ọwọ́ rẹ̀ sì bọ̀ sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ èkejì. Síbẹ̀ àwọn Farisi jáde lọ pe ìpàdé láti dìtẹ̀ mú un àti bí wọn yóò ṣe pa Jesu.