Mat 12:24-28
Mat 12:24-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn nigbati awọn Farisi gbọ́, nwọn wipe, Ọkunrin yi kò lé awọn ẹmi èṣu jade, bikoṣe nipa Beelsebubu, olori awọn ẹmi èṣu. Jesu si mọ̀ ìronu wọn, o si wi fun wọn pe, Ijọba ki ijọba ti o ba yapa si ara rẹ̀, a sọ ọ di ahoro; ilukilu tabi ilekile ti o ba yapa si ara rẹ̀ kì yio duro. Bi Satani ba si nlé Satani jade, o yapa si ara rẹ̀; ijọba rẹ̀ yio ha ṣe le duro? Bi o ba si ṣepe nipa Beelsebubu li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, nipa tali awọn ọmọ nyin fi nlé wọn jade? nitorina ni nwọn o fi ma ṣe onidajọ nyin. Ṣugbọn bi o ba ṣe pe Ẹmí Ọlọrun li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, njẹ ijọba Ọlọrun de ba nyin.
Mat 12:24-28 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn nígbà tí àwọn Farisi gbọ́, wọ́n ní, “Ojú lásán kọ́ ni ọkunrin yìí fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde; agbára Beelisebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó ń lò.” Ṣugbọn Jesu mọ ohun tí wọn ń rò. Ó bá sọ fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó bá gbé ogun ti ara rẹ̀ yóo parun. Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ìlúkílùú tabi ilékílé tí àwọn eniyan ibẹ̀ bá ń bá ara wọn jà yóo tú. Bí Satani bá ń lé Satani jáde, ara rẹ̀ ni ó ń gbé ogun tì. Báwo ni ìjọba rẹ̀ ṣe lè dúró? Bí ó bá jẹ́ pé agbára Beelisebulu ni èmi fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, agbára wo ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde? Nítorí náà, àwọn ọmọ yín ni yóo ṣe onídàájọ́ yín. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé nípa Ẹ̀mí Ọlọrun ni mo fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọrun ti dé ba yín.
Mat 12:24-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Nípa Beelsebulu nìkan, tí í ṣe ọba ẹ̀mí èṣù ni ọkùnrin yìí fi lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.” Jesu tí ó mọ èrò wọn, ó wí fún wọn pé, “Ìjọbakíjọba tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ yóò parun, ìlúkílùú tàbí ilékílé tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ kì yóò dúró. Bí èṣù bá sì ń lé èṣù jáde, a jẹ́ wí pé, ó ń yapa sí ara rẹ̀. Ìjọba rẹ yóò ha ṣe le dúró? Àti pé, bi èmi bá ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde nípa Beelsebulu, nípa ta ni àwọn ènìyàn yín fi ń lé wọn jáde? Nítorí náà ni wọn yóò ṣe má ṣe ìdájọ́ yín. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé nípa Ẹ̀mí Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín.