Mat 12:1-37
Mat 12:1-37 Bibeli Mimọ (YBCV)
LAKOKÒ na ni Jesu là ãrin oko ọkà lọ li ọjọ isimi; ebi si npa awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, nwọn si bẹ̀rẹ si ima ya ipẹ́ ọkà, nwọn si njẹ. Ṣugbọn nigbati awọn Farisi ri i, nwọn wi fun u pe, Wò o, awọn ọmọ-ẹhin rẹ nṣe eyi ti kò yẹ lati ṣe li ọjọ isimi. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò ti kà ohun ti Dafidi ṣe, nigbati ebi npa a, ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀: Bi o ti wọ̀ ile Ọlọrun lọ, ti o si jẹ akara ifihàn, eyiti kò tọ́ fun u lati jẹ, ati fun awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀, bikoṣe fun kìki awọn alufa? Tabi ẹnyin ko ti kà a ninu ofin, bi o ti ṣe pe lọjọ isimi awọn alufa ti o wà ni tẹmpili mbà ọjọ isimi jẹ ti nwọn si wà li aijẹbi? Ṣugbọn mo wi fun nyin pe, ẹniti o jù tẹmpili lọ mbẹ nihin. Ṣugbọn ẹnyin iba mọ̀ ohun ti eyi jẹ: Anu li emi nfẹ ki iṣe ẹbọ; ẹnyin kì ba ti dá awọn alailẹṣẹ lẹbi. Nitori Ọmọ-enia jẹ́ Oluwa ọjọ isimi. Nigbati o si kuro nibẹ̀, o lọ sinu sinagogu wọn. Si kiyesi i, ọkunrin kan wà nibẹ̀, ti ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Nwọn si bi i pe, O ha tọ́ lati mu-ni-larada li ọjọ isimi? ki nwọn ki o le fẹ ẹ li ẹfẹ̀. O si wi fun wọn pe, Ọkunrin wo ni iba ṣe ninu nyin, ti o li agutan kan, bi o ba si bọ́ sinu ihò li ọjọ isimi, ti ki yio dì i mu, ki o si fà a soke? Njẹ melomelo li enia san jù agutan lọ? nitorina li o ṣe tọ́ lati mã ṣe rere li ọjọ isimi. Nitorina li o wi fun ọkunrin na pe, Na ọwọ́ rẹ. On si nà a; ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò rẹ̀ gẹgẹ bi ekeji. Nigbana li awọn Farisi jade lọ, nwọn si gbìmọ nitori rẹ̀, bi awọn iba ti ṣe pa a. Nigbati Jesu ṣi mọ̀, o yẹ̀ ara rẹ̀ kuro nibẹ̀; ọ̀pọ ijọ enia tọ̀ ọ lẹhin, o si mu gbogbo wọn larada. O si kìlọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe fi on hàn: Ki eyi ti a ti ẹnu wolĩ Isaiah wi ki o ba le ṣẹ, pe, Wo iranṣẹ mi, ẹniti mo yàn; ayanfẹ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi: Emi o fi ẹmí mi fun u, yio si fi idajọ hàn fun awọn keferi. On kì yio jà, kì yio si kigbe; bẹ̃li ẹnikẹni kì yio gbọ́ ohùn rẹ̀ ni igboro. Iyè fifọ́ ni on kì yio ṣẹ́, owu fitila ti nru ẹ̃fin nì on kì yio si pa, titi yio fi mu idajọ dé iṣẹgun. Orukọ rẹ̀ li awọn keferi yio ma gbẹkẹle. Nigbana li a gbé ọkunrin kan ti o li ẹmi èṣu, ti o fọju, ti o si yadi, wá sọdọ rẹ̀; o si mu u larada, ti afọju ati odi na sọ̀rọ ti o si riran. Ẹnu si yà gbogbo enia, nwọn si wipe, Ọmọ Dafidi kọ́ yi? Ṣugbọn nigbati awọn Farisi gbọ́, nwọn wipe, Ọkunrin yi kò lé awọn ẹmi èṣu jade, bikoṣe nipa Beelsebubu, olori awọn ẹmi èṣu. Jesu si mọ̀ ìronu wọn, o si wi fun wọn pe, Ijọba ki ijọba ti o ba yapa si ara rẹ̀, a sọ ọ di ahoro; ilukilu tabi ilekile ti o ba yapa si ara rẹ̀ kì yio duro. Bi Satani ba si nlé Satani jade, o yapa si ara rẹ̀; ijọba rẹ̀ yio ha ṣe le duro? Bi o ba si ṣepe nipa Beelsebubu li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, nipa tali awọn ọmọ nyin fi nlé wọn jade? nitorina ni nwọn o fi ma ṣe onidajọ nyin. Ṣugbọn bi o ba ṣe pe Ẹmí Ọlọrun li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, njẹ ijọba Ọlọrun de ba nyin. Tabi ẹnikan yio ti ṣe wọ̀ ile alagbara lọ, ki o si kó o li ẹrù, bikoṣepe o kọ́ dè alagbara na? nigbana ni yio si kó o ni ile. Ẹniti kò ba wà pẹlu mi, o nṣe odi si mi; ẹniti kò ba si bá mi kopọ̀, o nfọnka. Nitorina ni mo wi fun nyin, gbogbo irú ẹ̀ṣẹ-kẹṣẹ ati ọrọ-odi li a o darijì enia; ṣugbọn ọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, on li a ki yio darijì enia. Ẹnikẹni ti o ba nsọrọ-odi si Ọmọ-enia, a o dari rẹ̀ jì i; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba nsọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, a ki yio dari rẹ̀ jì i li aiye yi, ati li aiye ti mbọ̀. Sọ igi di rere, eso rẹ̀ a si di rere; tabi sọ igi di buburu, eso rẹ̀ a si di buburu: nitori nipa eso li ã fi mọ igi. Ẹnyin ọmọ paramọlẹ, ẹnyin ti iṣe enia buburu yio ti ṣe le sọ̀rọ rere? nitori ninu ọ̀pọlọpọ ohun inu li ẹnu isọ. Enia rere lati inu iṣura rere ọkàn rẹ̀ ni imu ohun rere jade wá: ati enia buburu lati inu iṣura buburu ni imu ohun buburu jade wá. Ṣugbọn mo wi fun nyin, gbogbo ọ̀rọ wère ti enia nsọ, nwọn o jihìn rẹ̀ li ọjọ idajọ. Nitori nipa ọ̀rọ rẹ li a o fi da ọ lare, nipa ọ̀rọ rẹ li a o si fi da ọ lẹbi.
Mat 12:1-37 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò náà Jesu ń la oko ọkà kan kọjá ní Ọjọ́ Ìsinmi àwọn Juu. Ebi ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà, wọ́n ń jẹ ẹ́. Nígbà tí àwọn Farisi rí i, wọ́n wí fún un pé, “Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò tọ́ láti ṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi.” Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò kà nípa ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀? Bí wọ́n ti wọ inú ilé Ọlọrun lọ, tí wọ́n sì jẹ burẹdi tí ó wà lórí tabili níwájú Oluwa, èyí tí ó lòdì sí òfin fún òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ láti jẹ bíkòṣe fún àwọn alufaa nìkan? Tabi ẹ kò kà ninu ìwé Òfin pé iṣẹ́ àwọn alufaa ninu Tẹmpili ní Ọjọ́ Ìsinmi a máa mú wọn ba Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́? Sibẹ wọn kò jẹ̀bi. Mo sọ fun yín pé ẹni tí ó ju Tẹmpili lọ ló wà níhìn-ín yìí. Bí ó bá jẹ́ pé ìtumọ̀ gbolohun yìí ye yín ni, pé: ‘Àánú ṣíṣe ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ rírú’ ẹ kì bá tí dá ẹ̀bi fún aláìṣẹ̀. Nítorí Ọmọ-Eniyan ni Oluwa Ọjọ́ Ìsinmi.” Lẹ́yìn èyí, Jesu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí inú ilé ìpàdé wọn. Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Wọ́n bi í pé, “Ṣé ó bá òfin mu láti ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi?” Kí wọ́n baà lè rí ẹ̀sùn fi kàn án ni wọ́n fi bèèrè ìbéèrè yìí. Ó bá bi wọ́n báyìí pé, “Ta ni ninu yín tí yóo ní aguntan kan, bí ọ̀kan náà bá jìn sí kòtò ní Ọjọ́ Ìsinmi, tí kò ní fà á jáde? Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí eniyan ti sàn ju aguntan lọ, ó tọ́ láti ṣe rere ní Ọjọ́ Ìsinmi.” Ó bá sọ fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó bá nà án. Ọwọ́ rẹ̀ bá bọ́ sípò gẹ́gẹ́ bí ekeji. Àwọn Farisi bá jáde lọ láti gbèrò nípa rẹ̀, bí wọn óo ṣe lè pa á. Nígbà tí Jesu mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó bá kúrò níbẹ̀. Ọpọlọpọ eniyan sì tẹ̀lé e, ó sì wo gbogbo wọn sàn. Ó kìlọ̀ fún wọn kí wọn má ṣe polongo òun, kí ọ̀rọ̀ tí wolii Aisaya sọ lè ṣẹ pé, “Wo ọmọ mi tí mo yàn, àyànfẹ́ mi, ẹni tí ọkàn mi yọ̀ mọ́ Èmi óo fi Ẹ̀mí mi sí i lára, yóo kéde ìdájọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu. Kò ní ṣàròyé, bẹ́ẹ̀ ni kò ní pariwo, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò ní gbọ́ ohùn rẹ̀ ní títì. Kò ní dá igi tẹ́ẹ́rẹ́ tí ó tẹ̀ sí meji. Kò ní pa iná tí ó ń jó bẹ́lúbẹ́lú, títí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ yóo fi borí. Ninu orúkọ rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu yóo ní ìrètí.” Nígbà náà wọ́n mú ẹnìkan wá sọ́dọ̀ Jesu tí ó ní ẹ̀mí èṣù; ẹ̀mí èṣù yìí ti fọ́ ọ lójú, ó sì mú kí ó yadi. Jesu bá wò ó sàn; ọkunrin náà bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó sì ríran. Ẹnu ya gbogbo àwọn eniyan, wọ́n ń wí pé, “Ó ha lè jẹ́ pé ọmọ Dafidi nìyí bí?” Ṣugbọn nígbà tí àwọn Farisi gbọ́, wọ́n ní, “Ojú lásán kọ́ ni ọkunrin yìí fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde; agbára Beelisebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó ń lò.” Ṣugbọn Jesu mọ ohun tí wọn ń rò. Ó bá sọ fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó bá gbé ogun ti ara rẹ̀ yóo parun. Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ìlúkílùú tabi ilékílé tí àwọn eniyan ibẹ̀ bá ń bá ara wọn jà yóo tú. Bí Satani bá ń lé Satani jáde, ara rẹ̀ ni ó ń gbé ogun tì. Báwo ni ìjọba rẹ̀ ṣe lè dúró? Bí ó bá jẹ́ pé agbára Beelisebulu ni èmi fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, agbára wo ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde? Nítorí náà, àwọn ọmọ yín ni yóo ṣe onídàájọ́ yín. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé nípa Ẹ̀mí Ọlọrun ni mo fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọrun ti dé ba yín. “Báwo ni ẹnìkan ṣe lè wọ ilé alágbára lọ, kí ó kó o lẹ́rù, bí kò bá kọ́kọ́ de alágbára náà? Bí ó bá kọ́kọ́ dè é ni yóo tó lè kó o lẹ́rù. “Ẹni tí kò bá ṣe tèmi, ó lòdì sí mi. Ẹni tí kò bá máa bá mi kó nǹkan jọ, ó ń fọ́nká ni. Ìdí nìyí tí mo fi sọ fun yín pé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ati gbogbo ìsọ̀rọ̀ òdì ni a óo dárí rẹ̀ ji eniyan; ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní rí ìdáríjì. Ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ tí kò dára sí Ọmọ-Eniyan yóo rí ìdáríjì. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ tí kò dára sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní rí ìdáríjì láyé yìí ati ní ayé tí ń bọ. “Bákan-meji ni. Ninu kí ẹ tọ́jú igi, kí ó dára, kí èso rẹ̀ sì dára, tabi kí ẹ ba igi jẹ́, kí èso rẹ̀ náà sì bàjẹ́. Èso igi ni a fi ń mọ igi. Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀ yìí! Báwo ni ọ̀rọ̀ yín ti ṣe lè dára nígbà tí ẹ̀yin fúnra yín kò dára? Nítorí ohun tí ó bá kún inú ọkàn ni ẹnu ń sọ jáde. Ẹni rere a máa sọ ọ̀rọ̀ rere jáde láti inú ìṣúra rere; eniyan burúkú a sì máa sọ ọ̀rọ̀ burúkú jáde láti inú ìṣúra burúkú. “Ṣugbọn mo sọ fun yín pé gbogbo ọ̀rọ̀ tí eniyan bá ń sọ láì ronú ni yóo dáhùn fún ní ọjọ́ ìdájọ́. Nítorí nípa ọ̀rọ̀ rẹ ni a óo fi dá ọ láre; nípa ọ̀rọ̀ rẹ ni a óo sì fi dá ọ lẹ́bi.”
Mat 12:1-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní àkókò náà ni Jesu ń la àárín oko ọkà kan lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ebi sì ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i ya orí ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́. Nígbà tí àwọn Farisi rí èyí. Wọ́n wí fún pé, “Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi.” Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò ha ka ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa á àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó wọ inú ilé Ọlọ́run, òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ àkàrà tí a yà sọ́tọ̀, èyí tí kò yẹ fún wọn láti jẹ, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà nìkan. Tàbí ẹ̀yin kò ti kà á nínú òfin pé ní ọjọ́ ìsinmi, àwọn àlùfáà tí ó wà ní tẹmpili ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ tí wọ́n sì wà láìjẹ̀bi. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, ẹni tí ó pọ̀ ju tẹmpili lọ wà níhìn-ín. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí, ‘Àánú ni èmi ń fẹ́ kì í ṣe ẹbọ,’ ẹ̀yin kì bá tí dá aláìlẹ́ṣẹ̀ lẹ́bi. Nítorí pé Ọmọ Ènìyàn jẹ́ Olúwa ọjọ́ ìsinmi.” Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀ ó lọ sí Sinagọgu wọn, ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ wà níbẹ̀. Wọ́n ń wá ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jesu, wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti mú ènìyàn láradá ní ọjọ́ ìsinmi?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ wí pé bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ní àgùntàn kan ṣoṣo, tí ó sì bọ́ sínú kòtò ní ọjọ́ ìsinmi, ǹjẹ́ kì yóò dìímú, kí ó sì fà á jáde. Ǹjẹ́ mélòó mélòó ní ènìyàn ní iye lórí ju àgùntàn kan lọ! Nítorí náà ó yẹ láti ṣe rere ní ọjọ́ ìsinmi.” Nígbà náà, ó sì wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ,” bí òun sì ti nà án, ọwọ́ rẹ̀ sì bọ̀ sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ èkejì. Síbẹ̀ àwọn Farisi jáde lọ pe ìpàdé láti dìtẹ̀ mú un àti bí wọn yóò ṣe pa Jesu. Nígbà tí Jesu sì mọ̀, ó yẹra kúrò níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú gbogbo àwọn aláìsàn láradá. Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n kí ó má ṣe fi òun hàn. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ èyí tí wòlíì Isaiah sọ nípa rẹ̀ pé: “Ẹ wo ìránṣẹ́ mi ẹni tí mo yàn. Àyànfẹ́ mi ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi; èmi yóò fi ẹ̀mí mi fún un. Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ àwọn kèfèrí. Òun kì yóò jà, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò kígbe; ẹnikẹ́ni kì yóò gbọ́ ohùn rẹ ní ìgboro. Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́, àti òwú-fìtílà tí ń jó tan an lọ lòun kì yóò fẹ́ pa. Títí yóò fi mú ìdájọ́ dé ìṣẹ́gun. Ní orúkọ rẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò fi ìrètí wọn sí.” Nígbà náà ni wọ́n mú ọkùnrin kan tó ni ẹ̀mí èṣù tọ̀ ọ́ wá, tí ó afọ́jú, tí ó tún ya odi. Jesu sì mú un láradá kí ó le sọ̀rọ̀, ó sì ríran. Ẹnu sì ya gbogbo àwọn ènìyàn. Wọ́n wí pé, “Èyí ha lè jẹ́ Ọmọ Dafidi bí?” Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Nípa Beelsebulu nìkan, tí í ṣe ọba ẹ̀mí èṣù ni ọkùnrin yìí fi lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.” Jesu tí ó mọ èrò wọn, ó wí fún wọn pé, “Ìjọbakíjọba tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ yóò parun, ìlúkílùú tàbí ilékílé tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ kì yóò dúró. Bí èṣù bá sì ń lé èṣù jáde, a jẹ́ wí pé, ó ń yapa sí ara rẹ̀. Ìjọba rẹ yóò ha ṣe le dúró? Àti pé, bi èmi bá ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde nípa Beelsebulu, nípa ta ni àwọn ènìyàn yín fi ń lé wọn jáde? Nítorí náà ni wọn yóò ṣe má ṣe ìdájọ́ yín. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé nípa Ẹ̀mí Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín. “Tàbí, báwo ni ẹnikẹ́ni ṣe lè wọ ilé alágbára lọ kí ó sì kó ẹrù rẹ̀, bí kò ṣe pé ó kọ́kọ́ di alágbára náà? Nígbà náà ni ó tó lè kó ẹrù rẹ̀ lọ. “Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, òun lòdì sí mi, ẹni tí kò bá mi kójọpọ̀ ń fọ́nká. Nítorí èyí, mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀-òdì ni a yóò dárí rẹ̀ jí ènìyàn, ṣùgbọ́n ìṣọ̀rọ̀-òdì-sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní ìdáríjì. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí Ọmọ ènìyàn, a ó dáríjì í, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀-òdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kì yóò dáríjì í, ìbá à ṣe ní ayé yìí tàbí ní ayé tí ń bọ̀. “E sọ igi di rere, èso rẹ̀ a sì di rere tàbí kí ẹ sọ igi di búburú, èso rẹ a sì di búburú, nítorí nípa èso igi ni a ó fi mọ̀ igi. Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀, báwo ni ẹ̀yin tí ẹ jẹ búburú ṣe lè sọ̀rọ̀ rere? Ọkàn ènìyàn ni ó ń darí irú ọ̀rọ̀ tí ó lè jáde lẹ́nu rẹ̀. Ẹni rere láti inú yàrá ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá: àti ẹni búburú láti inú ìṣúra búburú ni; mu ohun búburú jáde wá. Ṣùgbọ́n, mo sọ èyí fún yín, ẹ̀yin yóò jíyìn gbogbo ìsọkúsọ yín ní ọjọ́ ìdájọ́. Nítorí nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín ni a fi dá yin láre, nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín sì ni a ó fi dá yin lẹ́bi.”