Mat 12:1-13

Mat 12:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

LAKOKÒ na ni Jesu là ãrin oko ọkà lọ li ọjọ isimi; ebi si npa awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, nwọn si bẹ̀rẹ si ima ya ipẹ́ ọkà, nwọn si njẹ. Ṣugbọn nigbati awọn Farisi ri i, nwọn wi fun u pe, Wò o, awọn ọmọ-ẹhin rẹ nṣe eyi ti kò yẹ lati ṣe li ọjọ isimi. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò ti kà ohun ti Dafidi ṣe, nigbati ebi npa a, ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀: Bi o ti wọ̀ ile Ọlọrun lọ, ti o si jẹ akara ifihàn, eyiti kò tọ́ fun u lati jẹ, ati fun awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀, bikoṣe fun kìki awọn alufa? Tabi ẹnyin ko ti kà a ninu ofin, bi o ti ṣe pe lọjọ isimi awọn alufa ti o wà ni tẹmpili mbà ọjọ isimi jẹ ti nwọn si wà li aijẹbi? Ṣugbọn mo wi fun nyin pe, ẹniti o jù tẹmpili lọ mbẹ nihin. Ṣugbọn ẹnyin iba mọ̀ ohun ti eyi jẹ: Anu li emi nfẹ ki iṣe ẹbọ; ẹnyin kì ba ti dá awọn alailẹṣẹ lẹbi. Nitori Ọmọ-enia jẹ́ Oluwa ọjọ isimi. Nigbati o si kuro nibẹ̀, o lọ sinu sinagogu wọn. Si kiyesi i, ọkunrin kan wà nibẹ̀, ti ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Nwọn si bi i pe, O ha tọ́ lati mu-ni-larada li ọjọ isimi? ki nwọn ki o le fẹ ẹ li ẹfẹ̀. O si wi fun wọn pe, Ọkunrin wo ni iba ṣe ninu nyin, ti o li agutan kan, bi o ba si bọ́ sinu ihò li ọjọ isimi, ti ki yio dì i mu, ki o si fà a soke? Njẹ melomelo li enia san jù agutan lọ? nitorina li o ṣe tọ́ lati mã ṣe rere li ọjọ isimi. Nitorina li o wi fun ọkunrin na pe, Na ọwọ́ rẹ. On si nà a; ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò rẹ̀ gẹgẹ bi ekeji.

Mat 12:1-13 Yoruba Bible (YCE)

Ní àkókò náà Jesu ń la oko ọkà kan kọjá ní Ọjọ́ Ìsinmi àwọn Juu. Ebi ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà, wọ́n ń jẹ ẹ́. Nígbà tí àwọn Farisi rí i, wọ́n wí fún un pé, “Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò tọ́ láti ṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi.” Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò kà nípa ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀? Bí wọ́n ti wọ inú ilé Ọlọrun lọ, tí wọ́n sì jẹ burẹdi tí ó wà lórí tabili níwájú Oluwa, èyí tí ó lòdì sí òfin fún òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ láti jẹ bíkòṣe fún àwọn alufaa nìkan? Tabi ẹ kò kà ninu ìwé Òfin pé iṣẹ́ àwọn alufaa ninu Tẹmpili ní Ọjọ́ Ìsinmi a máa mú wọn ba Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́? Sibẹ wọn kò jẹ̀bi. Mo sọ fun yín pé ẹni tí ó ju Tẹmpili lọ ló wà níhìn-ín yìí. Bí ó bá jẹ́ pé ìtumọ̀ gbolohun yìí ye yín ni, pé: ‘Àánú ṣíṣe ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ rírú’ ẹ kì bá tí dá ẹ̀bi fún aláìṣẹ̀. Nítorí Ọmọ-Eniyan ni Oluwa Ọjọ́ Ìsinmi.” Lẹ́yìn èyí, Jesu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí inú ilé ìpàdé wọn. Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Wọ́n bi í pé, “Ṣé ó bá òfin mu láti ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi?” Kí wọ́n baà lè rí ẹ̀sùn fi kàn án ni wọ́n fi bèèrè ìbéèrè yìí. Ó bá bi wọ́n báyìí pé, “Ta ni ninu yín tí yóo ní aguntan kan, bí ọ̀kan náà bá jìn sí kòtò ní Ọjọ́ Ìsinmi, tí kò ní fà á jáde? Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí eniyan ti sàn ju aguntan lọ, ó tọ́ láti ṣe rere ní Ọjọ́ Ìsinmi.” Ó bá sọ fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó bá nà án. Ọwọ́ rẹ̀ bá bọ́ sípò gẹ́gẹ́ bí ekeji.

Mat 12:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní àkókò náà ni Jesu ń la àárín oko ọkà kan lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ebi sì ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i ya orí ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́. Nígbà tí àwọn Farisi rí èyí. Wọ́n wí fún pé, “Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi.” Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò ha ka ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa á àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó wọ inú ilé Ọlọ́run, òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ àkàrà tí a yà sọ́tọ̀, èyí tí kò yẹ fún wọn láti jẹ, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà nìkan. Tàbí ẹ̀yin kò ti kà á nínú òfin pé ní ọjọ́ ìsinmi, àwọn àlùfáà tí ó wà ní tẹmpili ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ tí wọ́n sì wà láìjẹ̀bi. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, ẹni tí ó pọ̀ ju tẹmpili lọ wà níhìn-ín. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí, ‘Àánú ni èmi ń fẹ́ kì í ṣe ẹbọ,’ ẹ̀yin kì bá tí dá aláìlẹ́ṣẹ̀ lẹ́bi. Nítorí pé Ọmọ Ènìyàn jẹ́ Olúwa ọjọ́ ìsinmi.” Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀ ó lọ sí Sinagọgu wọn, ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ wà níbẹ̀. Wọ́n ń wá ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jesu, wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti mú ènìyàn láradá ní ọjọ́ ìsinmi?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ wí pé bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ní àgùntàn kan ṣoṣo, tí ó sì bọ́ sínú kòtò ní ọjọ́ ìsinmi, ǹjẹ́ kì yóò dìímú, kí ó sì fà á jáde. Ǹjẹ́ mélòó mélòó ní ènìyàn ní iye lórí ju àgùntàn kan lọ! Nítorí náà ó yẹ láti ṣe rere ní ọjọ́ ìsinmi.” Nígbà náà, ó sì wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ,” bí òun sì ti nà án, ọwọ́ rẹ̀ sì bọ̀ sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ èkejì.