Mat 11:11-12
Mat 11:11-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ninu awọn ti a bí ninu obinrin, kò si ẹniti o ti idide jù Johanu Baptisti lọ; ṣugbọn ẹniti o kere julọ ni ijọba ọrun o pọ̀ ju u lọ. Lati igba ọjọ Johanu Baptisti wá, titi o fi di isisiyi ni ijọba ọrun di ifi agbara wọ, awọn alagbara si fi ipá gbà a.
Mat 11:11-12 Yoruba Bible (YCE)
Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ninu àwọn tí obinrin bí, kò ì tíì sí ẹnìkan tí ó ju Johanu Onítẹ̀bọmi lọ. Sibẹ, ẹni tí ó kéré jù lọ ní ìjọba Ọlọrun jù ú lọ. Láti àkókò tí Johanu Onítẹ̀bọmi ti bẹ̀rẹ̀ sí waasu títí di ìsinsìnyìí ni àwọn alágbára ti gbógun ti ìjọba ọ̀run, wọ́n sì fẹ́ fi ipá gbà á.
Mat 11:11-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lóòótọ́ ni mó wí fún yín, nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí ẹni tí ó tí í dìde tí ó ga ju Johanu onítẹ̀bọmi lọ, síbẹ̀ ẹni tí ó kéré jù ní ìjọba ọ̀run ni ó pọ̀jù ú lọ. Láti ìgbà ọjọ́ Johanu onítẹ̀bọmi títí di àkókò yìí ni ìjọba ọ̀run ti di à fi agbára wọ̀, àwọn alágbára ló ń fi ipá gbà á.