Mat 11:1-7
Mat 11:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, nigbati Jesu pari aṣẹ rẹ̀ tan fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejejila, o ti ibẹ̀ rekọja lati ma kọni, ati lati ma wasu ni ilu wọn gbogbo. Nigbati Johanu gburo iṣẹ Kristi ninu tubu, o rán awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ meji, O si wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a mã reti ẹlomiran? Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ, ẹ si sọ ohun wọnyi ti ẹnyin gbọ́, ti ẹ si ri fun Johanu: Awọn afọju nriran, awọn amukun si nrìn, a nwẹ̀ awọn adẹtẹ̀ mọ́, awọn aditi ngbọràn, a njí awọn okú dide, a si nwasu ihinrere fun awọn òtoṣi. Alabukun-fun si li ẹnikẹni ti kì yio ri ohun ikọsẹ ninu mi. Nigbati nwọn si lọ, Jesu bẹrẹ si sọ fun awọn enia niti Johanu pe, Kili ẹnyin jade lọ iwò ni ijù? Ifefe ti afẹfẹ nmì?
Mat 11:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn tí Jesu ti fi gbogbo ìlànà wọnyi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila tán, ó kúrò níbẹ̀ lọ sí àwọn ìlú wọn, ó ń kọ àwọn eniyan ó sì ń waasu. Johanu gbọ́ ninu ẹ̀wọ̀n nípa iṣẹ́ tí Jesu ń ṣe. Ó bá rán àwọn kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n lọ bi í pé, “Ṣé ìwọ ni ẹni tí ó ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ ròyìn ohun tí ẹ ti gbọ́ ati ohun tí ẹ ti rí fún Johanu. Ẹ sọ fún un pé, àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn arọ ń rìn, ara àwọn adẹ́tẹ̀ ń di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń waasu ìyìn rere fún àwọn talaka. Ẹni tí kò bá ṣiyèméjì nípa mi ṣe oríire!” Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Johanu pada lọ, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn eniyan nípa Johanu pé, “Kí ni ẹ jáde lọ wò ní aṣálẹ̀? Ṣé koríko tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síhìn-ín, sọ́hùn-ún? Rárá o!
Mat 11:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ìgbà tí Jesu sì ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá, ó ti ibẹ̀ rékọjá láti máa kọ́ni àti láti máa wàásù ní àwọn ìlú Galili gbogbo. Nígbà tí Johanu gbọ́ ohun tí Kristi ṣe nínú ẹ̀wọ̀n, ó rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣe ìwọ ni ẹni tó ń bọ̀ wá tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?” Jesu dáhùn ó wí pé, “Ẹ padà lọ, ẹ sì sọ fún Johanu ohun tí ẹ̀yin gbọ́, àti èyí tí ẹ̀yin rí. Àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ wọn, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì. Alábùkún fún ni ẹni tí kò rí ohun ìkọ̀sẹ̀ nípa mi.” Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ti lọ tán, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn nípa ti Johanu: “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò ní aginjù? Ewéko tí afẹ́fẹ́ ń mi?