Mat 10:7-10
Mat 10:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi ẹnyin ti nlọ, ẹ mã wasu, wipe, Ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ. Ẹ mã ṣe dida ara fun awọn olokunrùn, ẹ sọ awọn adẹtẹ̀ di mimọ́, ẹ si jí awọn okú dide, ki ẹ si mã lé awọn ẹmi èṣu jade: ọfẹ li ẹnyin gbà, ọfẹ ni ki ẹ fi funni. Ẹ máṣe pèse wura, tabi fadaka, tabi idẹ sinu aṣuwọn nyin; Tabi àpo fun àjo nyin, ki ẹ máṣe mu ẹwu meji, tabi bata, tabi ọpá; onjẹ oniṣẹ yẹ fun u.
Mat 10:7-10 Yoruba Bible (YCE)
Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa waasu pé, ‘Ìjọba ọ̀run súnmọ́ tòsí!’ Ẹ máa wo aláìsàn sàn; ẹ máa jí àwọn òkú dìde; ẹ máa sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́; ẹ máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ rí agbára wọnyi gbà. Ọ̀fẹ́ ni kí ẹ máa lò wọ́n. Ẹ má fi owó wúrà tabi fadaka tabi idẹ sinu àpò yín. Ẹ má mú àpò tí wọ́n fi ń ṣagbe lọ́wọ́ lọ. Ẹ má mú ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ meji. Ẹ má wọ bàtà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má mú ọ̀pá lọ́wọ́. Oúnjẹ òṣìṣẹ́ tọ́ sí i.
Mat 10:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ẹ̀yin ti ń lọ, ẹ máa wàásù yìí wí pé: ‘Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.’ Ẹ máa ṣe ìwòsàn fún àwọn aláìsàn, ẹ si jí àwọn òkú dìde, ẹ sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, kí ẹ sì máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fi fún ni. “Ẹ má ṣe mú wúrà tàbí fàdákà tàbí idẹ sínú àpò ìgbànú yín; Ẹ má ṣe mú àpò fún ìrìnàjò yín, kí ẹ má ṣe mú ẹ̀wù méjì, tàbí bàtà, tàbí ọ̀pá; oúnjẹ oníṣẹ́ yẹ fún un.