Mat 10:18-19
Mat 10:18-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
A o si mu nyin lọ siwaju awọn bãlẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹrí si wọn ati si awọn keferi. Nigbati nwọn ba si fi nyin le wọn lọwọ, ẹ máṣe ṣàniyan pe, bawo tabi kili ẹnyin o wi? nitoriti a o fi ohun ti ẹnyin o wi fun nyin ni wakati kanna.
Pín
Kà Mat 10Mat 10:18-19 Yoruba Bible (YCE)
Wọn yóo mu yín lọ jẹ́jọ́ níwájú àwọn gomina ati níwájú àwọn ọba nítorí tèmi, kí ẹ lè jẹ́rìí mi níwájú wọn ati níwájú àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu. Nígbà tí wọ́n bá mu yín lọ fún ìdájọ́, ẹ má dààmú nípa ohun tí ẹ óo sọ tabi bí ẹ óo ti sọ ọ́; nítorí Ọlọrun yóo fi ohun tí ẹ óo sọ fun yín ní àkókò náà.
Pín
Kà Mat 10