Mat 10:1-4
Mat 10:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI o si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejejila si ọdọ, o fi agbara fun wọn lori awọn ẹmi aimọ́, lati ma lé wọn jade ati lati ṣe iwòsan gbogbo àrun ati gbogbo aisan. Orukọ awọn aposteli mejila na ni wọnyi: Eyi ekini ni Simoni, ẹniti a npè ni Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀; Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀; Filippi, ati Bartolomeu; Tomasi, ati Matiu ti iṣe agbowode; Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Lebbeu, ẹniti a si npè ni Taddeu; Simoni ara Kana, ati Judasi Iskariotu, ẹniti o fi i hàn.
Mat 10:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila sọ́dọ̀, ó fún wọn ní àṣẹ láti máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ati láti máa ṣe ìwòsàn oríṣìíríṣìí àrùn ati àìsàn. Orúkọ àwọn aposteli mejila náà nìwọ̀nyí: Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀; lẹ́yìn náà Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀. Filipi ati Batolomiu, Tomasi ati Matiu agbowó-odè, Jakọbu ọmọ Alfeu ati Tadiu. Simoni ará Kenaani ati Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Mat 10:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jesu sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí ọ̀dọ̀; ó fún wọn ní àṣẹ láti lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde àti láti ṣe ìwòsàn ààrùn àti àìsàn gbogbo. Orúkọ àwọn aposteli méjèèjìlá náà ni wọ̀nyí: ẹni àkọ́kọ́ ni Simoni ẹni ti a ń pè ni Peteru àti arákùnrin rẹ̀ Anderu; Jakọbu ọmọ Sebede àti arákùnrin rẹ̀ Johanu. Filipi àti Bartolomeu; Tomasi àti Matiu agbowó òde; Jakọbu ọmọ Alfeu àti Taddeu; Simoni ọmọ ẹgbẹ́ Sealoti, Judasi Iskariotu, ẹni tí ó da Jesu.