Mat 10:1-11

Mat 10:1-11 Yoruba Bible (YCE)

Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila sọ́dọ̀, ó fún wọn ní àṣẹ láti máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ati láti máa ṣe ìwòsàn oríṣìíríṣìí àrùn ati àìsàn. Orúkọ àwọn aposteli mejila náà nìwọ̀nyí: Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀; lẹ́yìn náà Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀. Filipi ati Batolomiu, Tomasi ati Matiu agbowó-odè, Jakọbu ọmọ Alfeu ati Tadiu. Simoni ará Kenaani ati Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rẹ̀. Àwọn mejila yìí ni Jesu rán níṣẹ́, ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má gba ọ̀nà ìlú àwọn tí kì í ṣe Juu lọ; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má wọ ìlú àwọn ará Samaria. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ tọ àwọn aguntan ilé Israẹli tí ó sọnù lọ. Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa waasu pé, ‘Ìjọba ọ̀run súnmọ́ tòsí!’ Ẹ máa wo aláìsàn sàn; ẹ máa jí àwọn òkú dìde; ẹ máa sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́; ẹ máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ rí agbára wọnyi gbà. Ọ̀fẹ́ ni kí ẹ máa lò wọ́n. Ẹ má fi owó wúrà tabi fadaka tabi idẹ sinu àpò yín. Ẹ má mú àpò tí wọ́n fi ń ṣagbe lọ́wọ́ lọ. Ẹ má mú ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ meji. Ẹ má wọ bàtà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má mú ọ̀pá lọ́wọ́. Oúnjẹ òṣìṣẹ́ tọ́ sí i. “Bí ẹ bá dé ìlú tabi ìletò kan, ẹ fẹ̀sọ̀ wádìí bí ẹni tí ó yẹ kan bá wà níbẹ̀; lọ́dọ̀ rẹ̀ ni kí ẹ máa gbé títí ẹ óo fi kúrò níbẹ̀.

Mat 10:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Jesu sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí ọ̀dọ̀; ó fún wọn ní àṣẹ láti lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde àti láti ṣe ìwòsàn ààrùn àti àìsàn gbogbo. Orúkọ àwọn aposteli méjèèjìlá náà ni wọ̀nyí: ẹni àkọ́kọ́ ni Simoni ẹni ti a ń pè ni Peteru àti arákùnrin rẹ̀ Anderu; Jakọbu ọmọ Sebede àti arákùnrin rẹ̀ Johanu. Filipi àti Bartolomeu; Tomasi àti Matiu agbowó òde; Jakọbu ọmọ Alfeu àti Taddeu; Simoni ọmọ ẹgbẹ́ Sealoti, Judasi Iskariotu, ẹni tí ó da Jesu. Àwọn méjèèjìlá wọ̀nyí ni Jesu ran, ó sì pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe lọ sì ọ̀nà àwọn kèfèrí, ẹ má ṣe wọ̀ ìlú àwọn ará Samaria Ẹ kúkú tọ̀ àwọn àgùntàn ilé Israẹli tí ó nù lọ. Bí ẹ̀yin ti ń lọ, ẹ máa wàásù yìí wí pé: ‘Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.’ Ẹ máa ṣe ìwòsàn fún àwọn aláìsàn, ẹ si jí àwọn òkú dìde, ẹ sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, kí ẹ sì máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fi fún ni. “Ẹ má ṣe mú wúrà tàbí fàdákà tàbí idẹ sínú àpò ìgbànú yín; Ẹ má ṣe mú àpò fún ìrìnàjò yín, kí ẹ má ṣe mú ẹ̀wù méjì, tàbí bàtà, tàbí ọ̀pá; oúnjẹ oníṣẹ́ yẹ fún un. Ìlúkílùú tàbí ìletòkíletò tí ẹ̀yin bá wọ̀, ẹ wá ẹni ti ó bá yẹ níbẹ̀ rí, níbẹ̀ ni kí ẹ sì gbé nínú ilé rẹ̀ títí tí ẹ̀yin yóò fi kúrò níbẹ̀.