Mat 1:1-6
Mat 1:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
IWE iran Jesu Kristi, ọmọ Dafidi ọmọ Abrahamu. Abrahamu bí Isaaki; Isaaki si bí Jakọbu; Jakọbu si bí Juda ati awọn arakunrin rẹ̀; Juda si bí Faresi ati Sara ti Tamari; Faresi si bí Esromu; Esromu si bí Aramu; Aramu si bí Aminadabu; Aminadabu si bí Naaṣoni; Naaṣoni si bí Salmoni; Salmoni si bí Boasi ti Rakabu; Boasi si bí Obedi ti Rutu; Obedi si bí Jesse; Jesse si bí Dafidi ọba. Dafidi ọba si bí Solomoni lati ọdọ ẹniti o ti nṣe aya Uria
Mat 1:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Jesu Kristi, ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu. Abrahamu bí Isaaki, Isaaki bí Jakọbu, Jakọbu bí Juda ati àwọn arakunrin rẹ̀. Juda bí Peresi ati Sera, ìyá wọn ni Tamari. Peresi bí Hesironi, Hesironi bí Ramu. Ramu bí Aminadabu, Aminadabu bí Naṣoni, Naṣoni bí Salimoni. Salimoni bí Boasi, ìyá Boasi ni Rahabu, Boasi bí Obedi. Ìyá Obedi ni Rutu. Obedi bí Jese. Jese bí Dafidi ọba. Dafidi bí Solomoni. Aya Uraya tẹ́lẹ̀ ni ìyá Solomoni.
Mat 1:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwé ìran Jesu Kristi, ẹni tí í ṣe ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu: Abrahamu ni baba Isaaki; Isaaki ni baba Jakọbu; Jakọbu ni baba Juda àti àwọn arákùnrin rẹ̀, Juda ni baba Peresi àti Sera, Tamari sì ni ìyá rẹ̀, Peresi ni baba Hesroni: Hesroni ni baba Ramu; Ramu ni baba Amminadabu; Amminadabu ni baba Nahiṣoni; Nahiṣoni ni baba Salmoni; Salmoni ni baba Boasi, Rahabu sí ni ìyá rẹ̀; Boasi ni baba Obedi, Rutu sí ni ìyá rẹ̀; Obedi sì ni baba Jese; Jese ni baba Dafidi ọba.