Mal 3:7-12
Mal 3:7-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lati ọjọ awọn baba nyin wá li ẹnyin tilẹ ti yapa kuro ni ilàna mi, ti ẹ kò si pa wọn mọ. Ẹ yipada si ọdọ mi, Emi o si yipada si ọdọ nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Ṣugbọn ẹnyin wipe, nipa bawo li awa o yipada? Enia yio ha jà Ọlọrun li olè? ṣugbọn ẹnyin sa ti jà mi li olè. Ṣugbọn ẹnyin wipe, nipa bawo li awa fi jà ọ li olè? Nipa idamẹwa ati ọrẹ. Riré li a o fi nyin ré: nitori ẹnyin ti jà mi li olè, ani gbogbo orilẹ-ède yi. Ẹ mu gbogbo idamẹwa wá si ile iṣura, ki onjẹ ba le wà ni ile mi, ẹ si fi eyi dán mi wò nisisiyi, bi emi ki yio ba ṣi awọn ferese ọrun fun nyin, ki nsi tú ibukún jade fun nyin, tobẹ̃ ti ki yio si aye to lati gbà a. Emi o si ba ajẹnirun wi nitori nyin, on kì o si run eso ilẹ nyin, bẹ̃ni àjara nyin kì o rẹ̀ dànu, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Gbogbo orilẹ-ède ni yio si pè nyin li alabukún fun: nitori ẹnyin o jẹ ilẹ ti o wuni, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Mal 3:7-12 Yoruba Bible (YCE)
Láti ayé àwọn baba ńlá yín ni ẹ ti yapa kúrò ninu ìlànà mi, tí ẹ kò sì tẹ̀lé wọn mọ́. Ẹ̀yin ẹ yipada sí mi, èmi náà óo sì yipada si yín. Ṣugbọn ẹ̀ ń bèèrè pé, ‘Báwo ni a ti ṣe lè yipada?’ Ǹjẹ́ ó ṣeéṣe fún eniyan láti ja Ọlọrun lólè? Ṣugbọn ẹ̀ ń jà mí lólè. Ẹ sì ń bèèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni à ń gbà jà ọ́ lólè?’ Nípa ìdámẹ́wàá ati ọrẹ yín ni. Ègún wà lórí gbogbo yín nítorí pé gbogbo orílẹ̀-èdè yín ní ń jà mí lólè. Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá yín wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ baà lè wà ninu ilé mi. Ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ kí ẹ fi dán mi wò, bí n kò bá ní ṣí fèrèsé ọ̀run sílẹ̀, kí n sì tú ibukun jáde fun yín lọpọlọpọ, tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní sí ààyè tó láti gbà á. N kò ní jẹ́ kí kòkòrò ajẹnirun jẹ ohun ọ̀gbìn yín lóko, ọgbà àjàrà yín yóo sì so jìnwìnnì. Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa pè yín ní ẹni ibukun, ilẹ̀ yín yóo sì jẹ́ ilẹ̀ ayọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!”
Mal 3:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Láti ọjọ́ àwọn baba ńlá yín wá ni ẹ̀yin tilẹ̀ ti kọ ẹ̀yìn sí ìlànà mi, tí ẹ kò sì pa wọ́n mọ́. Ẹ padà wá sí ọ̀dọ̀ mi, Èmi yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa yóò ṣe padà?’ “Ènìyàn yóò ha ja Ọlọ́run ni olè bí? Síbẹ̀ ẹ̀yin ti jà mí ní olè. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe jà ọ́ ní olè?’ “Nípa ìdámẹ́wàá àti ọrẹ. Ríré ni a ó fi yín ré: gbogbo orílẹ̀-èdè yìí, nítorí ẹ̀yin ti jà mi lólè. Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ bá à lè wà ní ilé mi, ẹ fi èyí dán mi wò,” ní OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí, “kí ẹ sì wò bí èmi kò bá ní sí àwọn fèrèsé ọ̀run fún yin, kí èmi sì tú ìbùkún àkúnwọ́sílẹ̀ jáde fún yín, tó bẹ́ẹ̀ tí kì yóò sì ààyè láti gbà á. Èmi yóò sì bá kòkòrò ajẹnirun wí nítorí yín, òun kò sì ni run èso ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni àjàrà inú oko yín kò ní rẹ̀ dànù,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Nígbà náà ni gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì pè yín ni alábùkún fún, nítorí tiyín yóò jẹ́ ilẹ̀ tí ó wu ni,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí.