Mal 3:14-16
Mal 3:14-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin ti wipe, Asan ni lati sìn Ọlọrun: anfani kili o si wà, ti awa ti pa ilàna rẹ̀ mọ, ti awa si ti rìn ni igbãwẹ̀ niwaju Oluwa awọn ọmọ-ogun? Ṣugbọn nisisiyi awa pè agberaga li alabùkunfun; lõtọ awọn ti o nhùwa buburu npọ si i; lõtọ, awọn ti o dán Oluwa wò li a dá si. Nigbana li awọn ti o bẹ̀ru Oluwa mba ara wọn sọ̀rọ nigbakugba; Oluwa si tẹti si i, o si gbọ́, a si kọ iwe-iranti kan niwaju rẹ̀, fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa, ti nwọn si nṣe aṣaro orukọ rẹ̀.
Mal 3:14-16 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ sọ pé, ‘Kí eniyan máa sin Ọlọrun kò jámọ́ nǹkankan. Kò sì sí èrè ninu pípa òfin rẹ̀ mọ́ tabi ninu rírẹ ara wa sílẹ̀ níwájú OLUWA àwọn ọmọ ogun. Ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nisinsinyii ni pé: ó ń dára fún àwọn agbéraga; kì í sì í ṣe pé ó ń dára fún àwọn eniyan burúkú nìkan, ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá fi ìwà burúkú wọn dán Ọlọrun wò, kò sí nǹkankan tí ń ṣẹlẹ̀ sí wọn.’ ” Nígbà tí àwọn tí wọ́n bẹ̀rù OLUWA bá ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, OLUWA a máa tẹ́tí sí wọn, yóo sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn. Ó ní ìwé kan níwájú rẹ̀ ninu èyí tí àkọsílẹ̀ àwọn tí wọ́n bẹ̀rù OLUWA, tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀ wà.
Mal 3:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ẹ̀yin ti wí pé, ‘Asán ni láti sin Ọlọ́run. Kí ni àwa jẹ ní èrè, nígbà tí àwa ti pa ìlànà rẹ mọ́, tí àwa sì ń rìn kiri bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ní iwájú OLúWA àwọn ọmọ-ogun? Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí àwa pé agbéraga ni alábùkún fún Ní òtítọ́ ni àwọn ti ń ṣe búburú ń gbèrú sí i, kódà àwọn ti ó dán Ọlọ́run wò ni a dá sí.’ ” Nígbà náà ni àwọn tí ó bẹ̀rù OLúWA ń ba ara wọn sọ̀rọ̀, OLúWA sì tẹ́tí sí i, ó sì gbọ́. A sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀, fún àwọn tí o bẹ̀rù OLúWA, tiwọn sì bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀.