Mal 3:1-7

Mal 3:1-7 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA ní, “Wò ó! Mo rán òjíṣẹ́ mi ṣiwaju mi láti tún ọ̀nà ṣe fún mi. OLUWA tí ẹ sì ń retí yóo yọ lójijì sinu tẹmpili rẹ̀; iranṣẹ mi, tí ẹ sì tí ń retí pé kí ó wá kéde majẹmu mi, yóo wá.” Ṣugbọn, ta ló lè farada ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ tí ó bá dé? Àwọn wo ni wọn yóo lè dúró ní ọjọ́ tí ó bá yọ? Nítorí pé ó dàbí iná alágbẹ̀dẹ tí ń yọ́ irin, ati bí ọṣẹ alágbàfọ̀ tí ń fọ nǹkan mọ́. Yóo jókòó bí ẹni tí ń yọ́ fadaka, yóo fọ àwọn ọmọ Lefi mọ́ bíi wúrà ati fadaka, títí tí wọn yóo fi mú ẹbọ tí ó tọ́ wá fún OLUWA. Inú OLUWA yóo wá dùn sí ẹbọ Juda ati ti Jerusalẹmu nígbà náà bíi ti àtẹ̀yìnwá. OLUWA ní, “N óo wá ba yín láti ṣe ìdájọ́; n óo wá jẹ́rìí mọ́ àwọn oṣó ati àwọn alágbèrè, àwọn tí wọn ń búra èké ati àwọn tí wọn kì í san owó ọ̀yà pé, àwọn tí wọn ń ni àwọn opó ati àwọn aláìníbaba lára, ati àwọn tí wọn ń ṣi àwọn àlejò lọ́nà, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Nítorí pé èmi OLUWA kì í yipada, ni a kò fi tíì run ẹ̀yin ọmọ Jakọbu patapata. Láti ayé àwọn baba ńlá yín ni ẹ ti yapa kúrò ninu ìlànà mi, tí ẹ kò sì tẹ̀lé wọn mọ́. Ẹ̀yin ẹ yipada sí mi, èmi náà óo sì yipada si yín.

Mal 3:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Wò ó, Èmi yóò ran ìránṣẹ́ mi, yóò tún ọ̀nà ṣe ṣáájú mi. Nígbà náà ni OLúWA, tí ẹ̀yin ń wa, yóò dé ni òjijì sí tẹmpili rẹ̀; àní oníṣẹ́ májẹ̀mú náà, tí inú yín dùn sí, yóò dé,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. Ṣùgbọ́n ta ni o lè fi ara da ọjọ́ dídé rẹ̀? Ta ni yóò sì dúró nígbà tí ó bá fi ara hàn? Nítorí òun yóò dàbí iná ẹni tí ń da fàdákà àti bi ọṣẹ alágbàfọ̀: Òun yóò sì jókòó bí ẹni tí n yọ́, tí ó sì ń da fàdákà; yóò wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, yóò sì tún wọn dàbí wúrà àti fàdákà, kí wọn bá a lè mú ọrẹ òdodo wá fún OLúWA, nígbà náà ni ọrẹ Juda àti ti Jerusalẹmu yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún OLúWA, gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ àtijọ́, àti gẹ́gẹ́ bí ọdún ìgbàanì. “Èmi ó sì súnmọ́ yin fún ìdájọ́. Èmi yóò sì yára ṣe ẹlẹ́rìí sí àwọn oṣó, sí àwọn panṣágà, sí àwọn abúra èké, àti àwọn tí ó fi ọ̀yà alágbàṣe pọn wọn lójú, àti àwọn tí ó ni àwọn opó àti àwọn aláìní baba lára, àti sí ẹni tí kò jẹ́ kí àjèjì rí ìdájọ́ òdodo gbà, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi OLúWA kò yípadà. Nítorí náà ni a kò ṣe run ẹ̀yin ọmọ Jakọbu. Láti ọjọ́ àwọn baba ńlá yín wá ni ẹ̀yin tilẹ̀ ti kọ ẹ̀yìn sí ìlànà mi, tí ẹ kò sì pa wọ́n mọ́. Ẹ padà wá sí ọ̀dọ̀ mi, Èmi yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa yóò ṣe padà?’

Mal 3:1-7

Mal 3:1-7 YBCV