Mal 2:2
Mal 2:2 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi ẹnyin kì o ba gbọ́, ti ẹnyin kì o ba fi si aiya, lati fi ogo fun orukọ mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si rán egún si ori nyin, emi o si fi ibukun nyin ré, lõtọ mo ti fi ré na, nitori pe, ẹnyin kò fi i si ọkàn.
Pín
Kà Mal 2Mal 2:2 Yoruba Bible (YCE)
Bí ẹ kò bá ní gbọ́ràn, tí ẹ kò sì ní fi sọ́kàn láti fi ògo fún orúkọ mi, n óo mú ègún wá sórí yín, ati sórí àwọn ohun ìní yín. Mo tilẹ̀ ti mú ègún wá sórí àwọn ohun ìní yín, nítorí pé ẹ kò fi ọ̀rọ̀ mi sọ́kàn.
Pín
Kà Mal 2Mal 2:2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ẹ̀yin kò bá ni gbọ́, bí ẹ̀yin kò bá ní fi í sí àyà láti fi ọ̀wọ̀ fún orúkọ mi,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí; èmi yóò sì ran ègún sí orí yín, èmi yóò sì fi ìbùkún yín ré. Nítòótọ́ mó ti fi ré ná, nítorí pé, ẹ̀yin kò fi sí ọkàn yín láti bu ọlá fún mi.
Pín
Kà Mal 2