Mal 2:14-17
Mal 2:14-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ẹnyin wipe, Nitori kini? Nitori Oluwa ti ṣe ẹlẹri lãrin iwọ ati lãrin aya ewe rẹ, ẹniti iwọ ti nhùwa ẹ̀tan si: bẹ̃li ẹgbẹ́ rẹ li on sa iṣe, ati aya majẹmu rẹ. On kò ha ti ṣe ọkan? bẹ̃li on ni iyokù ẹmi. Ẽ si ti ṣe jẹ ọkan? ki on ba le wá iru-ọmọ bi ti Ọlọrun. Nitorina ẹ tọju ẹmi nyin, ẹ má si jẹ ki ẹnikẹni hùwa ẹ̀tan si aya ewe rẹ̀. Nitori Oluwa, Ọlọrun Israeli wipe, on korira ikọ̀silẹ: ẹnikan fi ìwa-ipá bò aṣọ rẹ̀ mọlẹ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nitorina ẹ ṣọ ẹmi nyin, ki ẹ má ṣe hùwa ẹ̀tan. Ẹnyin ti fi ọ̀rọ nyin dá Oluwa li agara. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ninu kini awa fi da a lagara? Nigbati ẹnyin wipe, Olukulùku ẹniti o ṣe ibi, rere ni niwaju Oluwa, inu rẹ̀ si dùn si wọn; tabi, nibo ni Ọlọrun idajọ gbe wà?
Mal 2:14-17 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀ ń bèèrè pé, “Kí ló dé tí kò fi gbà á?” Ìdí rẹ̀ ni pé, OLUWA ni ẹlẹ́rìí majẹmu tí ẹ dá pẹlu aya tí ẹ fẹ́ nígbà èwe yín, tí ẹ sì ṣe aiṣootọ sí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olùrànlọ́wọ́ yín ni, òun sì ni aya tí ẹ bá dá majẹmu. Ṣebí ara kan náà ati ẹ̀jẹ̀ kan náà ni Ọlọrun ṣe ìwọ pẹlu rẹ̀? Kí ló dé tí Ọlọrun fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí rẹ̀ ni pé, Ọlọrun ń fẹ́ irú ọmọ tí yóo jẹ́ tirẹ̀. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ má ṣe hùwà aiṣootọ sí aya tí ẹ fẹ́ nígbà èwe yín. “Mo kórìíra ìkọ̀sílẹ̀ láàrin tọkọtaya, mo kórìíra irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀ sí olólùfẹ́ ẹni. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe jẹ́ alaiṣootọ sí aya yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!” Ọ̀rọ̀ yín ti sú Ọlọrun, sibẹsibẹ ẹ̀ ń bèèrè pé, “Báwo ni a ṣe mú kí ọ̀rọ̀ wa sú u?” Nítorí ẹ̀ ń sọ pé, “Gbogbo àwọn tí wọn ń ṣe burúkú jẹ́ eniyan rere níwájú OLUWA, inú rẹ̀ sì dùn sí wọn.” Tabi nípa bíbèèrè pé, “Níbo ni Ọlọrun onídàájọ́ òdodo wà?”
Mal 2:14-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, “Nítorí kín ní?” Nítorí OLúWA ti ṣe ẹlẹ́rìí láàrín ìwọ àti láàrín aya èwe rẹ, ẹni tí ìwọ ti ń hùwà ẹ̀tàn sí i: bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkejì rẹ ni òun jẹ́, àti aya májẹ̀mú rẹ. Ọlọ́run kò ha ti ṣe wọ́n ní ọ̀kan? Ni ara àti ni ẹ̀mí tirẹ̀ ni. Èéṣe tí Ọlọ́run da yín lọ́kàn? Kí òun bá à lè wá irú-ọmọ bí ti Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ tọ́jú ẹ̀mí yín, ẹ má sì ṣe hùwà ẹ̀tàn sí aya èwe yín. “Ọkùnrin tí ó bá kórìíra, tí ó sì kọ ìyàwó rẹ̀,” Ṣe ìwà ipá sí ẹni tí ó yẹ kí ó dá ààbò bò, ni OLúWA Ọlọ́run Israẹli wí, Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ ẹ̀mí yín, kí ẹ má ṣe hùwà ẹ̀tàn. Ẹ̀yin ti fi ọ̀rọ̀ yín dá OLúWA ní agara. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, “Nínú kín ni àwa fi dá a ní agara?” Nígbà tí ẹ̀yìn wí pé, “Gbogbo ẹni tí ó ṣe ibi, rere ni níwájú OLúWA, inú rẹ̀ sì dùn sí wọn,” tàbí “Níbo ni Ọlọ́run ìdájọ́ gbé wà?”